Iru ki waa leleyii! Wọn ni Tinubu ko lọ sileewe girama to kọ silẹ fun Fasiti Chicago

Faith Adebọla

Ọgbẹni Phrank Shaibu, to jẹ  oluranlọwọ pataki lori eto iroyin fun Alaaji Atiku Abubaka ti sọ pe okoto irọ mi-in tun ti ja nipasẹ awọn iwe-ẹri ati akọọlẹ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, olori orileede wa, eyi ti Chicago State University, ko fun ọga oun, Alaaji Atiku Abubakar. O ṣalaye pe akọsilẹ naa fihan pe ileewe girama Government College, Eko, ni Tinubu kọ silẹ pe oun ti kawe sẹkọndiri pari, lọdun 1970.

Ninu iwe akọọlẹ to fi wọle si fasiti Chicago ọhun,  Aarẹ Tinubu kọ ọ sibẹ pe oun paasi idanwo ileewe girama (General Certificate of Education), ni ipele A-Level, oun si yege idanwo Chemistry ati Biology, bo tilẹ jẹ pe F loun ni ni Physics.

Amọ, ninu atẹjade kan ti Shuaibu fi lede lorukọ Atiku lori ọrọ yii, o ni: “Aṣiri tuntun tun leyii o, tori Tinubu ti kọkọ n sọ pe ileewe Government College, Ibadan, loun ti kawe pari.  Amọ awọn akẹkọọ-jade nileewe ọhun lawọn ko mọ ọn. Kekere waa ni eyi jẹ lẹgbẹẹ ti Eko yii, tori ọdun 1974 ni wọn da Government College Eko silẹ. Ṣe ka waa sọ pe Tinubu ti n lọ sileewe ọhun, o tiẹ ti kawe paasi nileewe naa ki wọn to o da a silẹ lọdun 1974 ni. Aa jẹ pe oniṣẹ-iyanu arabaribi ni wọn niyẹn o.” Gẹgẹ bo ṣe wi.

Ẹ oo ranti pe lẹyin ti eto idibo gbogbogboo ọdun yii waye ni Alaaji Atiku Abukakar kọri silẹ Amẹrika, nibi to ti rọ ile-ẹjọ United States District Court of Northern Illinois, lati paṣẹ fun Fasiti Chicago yii pe ki wọn ko iwe-ẹri ati akọọlẹ Tinubu boode foun, tori oun fẹẹ ṣayẹwo si i, oun si fẹẹ lo o lati fi ti ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun toun pe siwaju ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹ wa lẹsẹ lori abajade esi idibo sipo aarẹ, ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission, INEC, kede pe Tinubu, ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lo jawe olubori, ti wọn si ti ṣebura fun un sipo aarẹ Naijiria lọwọlọwọ.

Ibeere tawọn eeyan n beere ni pe ṣe Tinubu ko lọ sileewe girama ni abi ọtọ ni orukọ to wa niẹ ni ko jẹ ki o le gbe iwe-ẹri naa sita.

Yatọ si eyi, ipasipayọ oriṣiiriṣii lo wa ninu iwe ti Tinubu ko silẹ ni Fasiti Chicago to fi wọle kẹkọọ gboye nibẹ. Wọn ni obinrin ni wọn kọ sibẹ pe o ni iwe-ẹri ọhun. Yato si eleyii, ọdun ti Tinubu kọ sibẹ gẹ bii ọjọ ori yatọ si eyi to kọ sinu fọọmu to fi ranṣẹ sajọ eleto idibo.

Gbogbo awọn oriṣiiriṣii aṣiri to n tu jade yii n kọ ọpọ ọmọ Naijiria lominu, ti wọn si n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ idi ti Tinubu fi gba ile-ẹjọ lọ lorileede Amẹrika pe ki wọn ma ko iwe-ẹri oun silẹ niyi, ki kootu ma si ṣe sọ boya obinrin ni oun tabi ọkunrin, ko too di pe ile-ẹjọ da gbogbo ẹbẹ naa nu, ti wọn si ko iwe ọhun fun Atiku.

Atiku, to tẹwọ gba awọn ẹda iwe-ẹri naa nipasẹ agbẹjọro rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni oludije funpo aarẹ lẹgbẹ PDP, ninu eto idibo naa, oun lo si ṣepo keji ninu esi idibo ọhun.

Lẹyin ti Tiribuna to n gbọ awuyewuye to su yọ ninu eto idibo sipo aarẹ ti fidi ẹ mulẹ pe Tinubu lo yege loootọ, ni Atiku, ati Peter Obi, gba ile-ẹjọ tẹjọ maa n pẹkun si, iyẹn Supirimu kootu lọ.

Leave a Reply