Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iya agbalagba kan ni awọn oniṣẹ ibi kan ti pa nipakupa mọ’nu oko rẹ to wa niluu Kọstain, nijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun ta a wa yii.
ALAROYE gbọ lati ẹnu araalu kan ta a forukọ bo laṣiiri pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn eeyan ti n wa iya agbalagba naa nigba ti wọn reti rẹ titi ko pada de lati oko to lọ, ṣugbọọn ti wọn ko ri i ko pada wale.
O ni nnkan bii aago mọkanla alẹ lawọn araadugbo ti mama ti wọn n wa ọhun kọle si kofiri ọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Sunday Akọ̀pẹ to n yọ kẹlẹkẹlẹ layiika ile rẹ pẹlu mariwo ọpẹ lọwọ, eyi to fẹẹ so mọ iwaju ile naa.
Eyi lo jẹ ki wọn mu ọkunrin naa,ti wọn si ni ko maa ṣalaye ohun to fẹẹ fi mariwo ọpẹ ṣe niwaju onile. Ohun to tun ṣe awọn eeyan ni kayeefi ni ti foonu iya ti wọn n wa ọhun ti wọn ba ninu apo rẹ nigba ti wọn n yẹ ara rẹ wo.
A gbọ pe ọkunrin ọmọ Ibo naa ṣẹ kanlẹ nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lori bi iya arugbo ọhun ṣe rin, ati ibi to wọlẹ si. Wọn ni o gbọdọ ṣàlàyé ohun to fẹẹ fi mariwo ṣe laarin oru nile ẹni ti wọn ṣi n wa.
Ohun ti wọn lọkunrin to n ṣiṣẹ ọpẹ kikọ ọhun kọkọ tẹnu mọ ni pe oun ko mọ irin iya agbalagba naa, o ni ṣe loun ni ki oun waa wo o boya o ti pada dele.
Nigba tawọn araadugbo ṣe e titi ti ko jẹwọ fun wọn ni wọn lọọ fi ọrọ ọhun to awọn ẹgbẹ ọdẹ, ọmọ ẹgbẹ Oodua atawọn ọlọpaa to wa niluu Kọstain leti.
Nigba to pẹ ti wọn ti n fọrọ wa Sunday lẹnu wo lo pada sọ fun wọn pe ki i ṣe oun loun pa a, o ni awọn Fulani meji loun ri ti wọn fun iya oniyaa lọrun pa mọ inu oko nibi to ti n ṣiṣẹ.
Bayii ni wọn ni Sunday tun bẹrẹ si i da awọn ẹṣọ alaabo naa riboribo kaakiri inu igbo nigba ti wọn ni ko mu awọn lọ sibi ti oku mama ọhun wa.
O to bii aago mẹrin irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ko too ṣẹṣẹ mu wọn lọ si ojuko ibi to pa iya ọhun si.
Alaye ti obinrin tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣe fun wa ni pe bi eeyan tilẹ jẹ ori ahun, ko si ki onitọhun ma ṣomi loju pẹrẹpẹrẹ to ba foju kan oku iya agbalagba naa nibi ti wọn pa a si.
O ni o da bii ẹni pe aṣọ ni wọn fi fun un lọrun pa lati ẹyin, bẹẹ ni ẹjẹ kun gbogbo ẹnu rẹ, nibi to fẹyin lelẹ si, to si ṣiju soke. Wọn daṣọ bo o loju, wọn si ṣẹ ewe bo iyooku ara rẹ.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe ṣe ni wọn fipa ba mama ọhun lo pọ titi to fi ku, nitori awọn ko ba pata tabi awọtẹlẹ kankan nidii rẹ. O ni ki i ṣe igba àkọ́kọ́ ree tawọn amookunṣika kan n lọọ ka awọn obinrin mọ inu oko lati fipa ba wọn lo pọ.
O ni lati ẹyin ni wọn ti maa n daṣọ bo awọn obinrin to ba ti ko si wọn lọwọ loju ki wọn maa baa da wọn mọ titi wọn yoo fi fipa ba wọn sun tan.
Ọpọlọpọ awọn obinrin to wa ni Kọstain ati agbegbe rẹ lo ni wọn ko lori laya lati da lọọ ṣiṣẹ ninu oko mọ nitori ibẹru.
A gbọ pe Sunday ṣi wa ni ikawọ awọn ọlọpaa ilu Kọstain, lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ. O lawọn ko ni i pẹẹ fi afurasi naa ṣọwọ si olu ileeṣẹ awọn to wa l’Akurẹ.
Nigba ta a kan si Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o sọ fun akọroyin wa pe oun maa pe wa pada laipẹ, ṣùgbọ́n a ko ri i ko pe wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.