Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ọfọ lawọn alaṣẹ, oṣiṣẹ atawọn akẹkọọ Fasiti Ibadan (University of Ibadan), wa bayii pẹlu bi awọn ọdaju eeyan kan ṣe yinbọn pa ọkan ninu awọn olukọ wọn, Ọjọgbọn Ọpẹyẹmi Ajewọle, ti wọn si tun gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lọ.
Lasiko to n dari lọ sile ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn niṣẹlẹ ọhun waye.
ALAROYE gbọ pe nibudokọ ti wọn n pe ni Olorooro, lọna UI si Ọjọọ, nigboro Ibadan lawọn ẹruuku naa ti fi ọkada dabuu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ to n wa lọ niwaju, ti wọn si yinbọn mọ ọn.
Loju-ẹsẹ ni wọn ti wọ ọ silẹ ninu oko naa, ti wọn si gbe ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla rẹ sa lọ.
Ẹni tọpọ awọn ẹgbẹ ẹ tun maa n pe ni Iroko yii lọpọ awọn to mọ ọn ṣapejuwe gẹgẹ bii oniwapẹlẹ ati oninuure eeyan, to si jẹ alafẹ eeyan to ko ẹni gbogbo mọra ni.
Ọjọgbọn Ajewọle, to jẹ olukọ ẹka imọ nipa ọgbin igi lawujọ yii lo ti figba kan jẹ alakooso agba fun ọkan ninu awọn ilegbee awọn akẹkọọ ti wọn n pe ni Nnamdi Azikwe.
Ọkan ninu awọn akẹgbẹ oloogbe yii nidii iṣẹ olukọ olukọ fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fakọroyin wa, o ni, “loootọ ni, Iroko ti ku, l’Olorooro ni wọn ti pa a, tí wọn si gbe moto rẹ lọ”.