Iru ọmọ wo waa leyii, o si binu pa iya ati aburo rẹ

Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, ni ọkunrin kan, Somadina Orji, wa bayii, latari bo ṣe pa iya rẹ, Abilekọ Charity Orji, ati aburo rẹ, Omidan Ukamaka Orji, lori ọrọ ti ko to nnkan ni Umuagu Inyi, nijọba ibilẹ Rivers, nipinlẹ naa. Lẹyin to pa wọn tan lo bo oku wọn mọlẹ lẹyinkunle ọgba ile wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila yii.

Ọkan lara awọn adari agbegbe Inyi, Ọgbẹni Ben Obi, to ba awọn oniroyin ṣọrọ sọ pe lati bii ọṣẹ meloo kan sẹyin ni wahala naa ti bẹrẹ, iyẹn lasiko ti afurasi naa ni iṣoro pẹlu aburo rẹ ọkunrin kan.

O ni niṣe ni Somadina fẹẹ lu aburo rẹ yii ni nikan ni, ṣugbọn iya ko gba fun un, lo ba lọọ fẹjọ afurasi naa sun ọba ilu, ti Kabiyesi si paṣẹ pe ki wọn le afurasi naa kuro nile latari pe o fẹẹ pa aburo rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe lati bii ọṣẹ meji ṣẹyin lo ti dawati, aipẹ yii ni wọn lo tun wọ ilu ọhun wa, lo ba tun bẹrẹ ija pẹlu iya rẹ.

O ṣalaye siwaju pe iya afurasi yii lọọ ki awọn kan ti ọfọ bṣẹ ni abule keji, ṣugbọn bo ṣe dari sile lọsan-an ọjọ naa ni ọmọ rẹ, Somadina, pa a, to si lọọ bo o mọlẹ ẹyinkunle ile wọn. Aburo rẹ dari wọle, o n wa iya wọn, ṣugbọn o fura si ẹgbọn wọn yii, lo ba figbe ta.

Nigba ti wọn mu un, afurasi yii jẹwọ pe loootọ loun ti pa iya awọn, ati pe oun ti pa aburo oun lati bii ọṣẹ meji ṣẹyin, toun si ti bo awọn mejeeji mọlẹ lẹyinkunle. Oju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti mu afurasi yii. Awọn naa ni wọn pada hu oku awọn oloogbe mejeeji yii, ti wọn gbe e lọ si mọṣuari.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, DSP Daniel Ndukwe, ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, ni ọwọ ti tẹ afurasi gende-kunrin naa, Somadina Orji, to jẹ ọmọ bibi Igboariam, nipinlẹ Anambra, to pa iya rẹ ati aburo rẹ kan latara egboogi oloro to n mu.

O tẹsiwaju pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, tawọn yoo si foju rẹ ba ile-ẹjọ laipẹ.

Ben ni ko too di pe iya wọn yii ku, fufu lo n ta lati fi gbọ bukaata oun atawọn ọmọ.

Leave a Reply