Isiaq at’ọrẹ ẹ yoo pẹ lẹwọn o, kòkò ìdáná, kula ounjẹ ati ọkada ni wọn ji gbe

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti paṣẹ pe ki wọn sọ awọn afurasi adigunjale meji kan, Abubakar Isiaq, ati Kareem Ibrahim, sọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu naa. Koko ti wọn fi n dáná atawọn eroja miiran ni wọn lọọ ji gbe lagbegbe Egbèjìlá.

Ajọ sifu difẹnsi, ẹka ipinlẹ Kwara, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe Abilekọ Abdullah Mariam, lo mu ẹsun awọn olujẹjọ naa wa si ọfiisi awọn. O ni awọn adigunjale kan wọ agboole oun to wa lagbegbe Egbèjìlá, niluu Ilọrin, ti wọn si ko awọn koko ìdáná ńlá kan, gẹnẹretọ ńlá kan, àwọn kúlà oúnjẹ ńlá mẹrin, ọkada Bajaj kan ati foonu andirọidi meji, ti iwadii si fihan pe Abubakar to jẹ ọrẹ Ibrahim lo ta foonu naa fun Ibrahim.

Eyi lo mu ki ajọ sifu difẹnsi tọpa foonu naa de ọdọ Ibrahim, oun  lo ṣokunfa bi wọn ṣe ri awọn afurasi naa mu.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni ẹsun ọdaran, igbimọ-pọ ṣisẹ buruku, ikọja aaye, jija ile onile ati gbigba ẹru ole.

Agbefọba to n ṣoju NSCDC ni kootu, Stephen Tsado, rọ adajọ pe ko ju awọn afurasi ọhun sẹwọn titi ti iwadii yoo fi pari.

Ṣugbọn agbẹjọro awọn afurasi naa, Toyin Ọnaọlapọ, rọ ile-ẹjọ lati ko fun awọn onibara rẹ ni beeli pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ. Ṣugbọn Onidaajọ Kọlawọle Aluko ko gbọ ẹbẹ Ọnaọlapọ.

O paṣẹ pe ki wọn sọ awọn mejeeji sọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

 

Leave a Reply