Jọkẹ Amọri
Kayeefi lọrọ ọhun ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to gbọ pe wolii kan to tun jẹ sọrọsọrọ ori redio nipinlẹ Ondo, Gbenga Filani, fipa ba alaboyun ti oyun oṣu marun-un wa ninu rẹ lo pọ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii ni ṣọọṣi rẹ to wa ni Ijọka, niluu Akurẹ.
Ọkunrin naa lo maa n ṣe eto ori redio kan ti wọn n pe ni ‘Owuyẹ’ niluu Akurẹ, to si tun ni eto mi-in to maa n ṣe lori redio kan ni Ikẹrẹ-Ekiti.
Gẹgẹ bi awọn to mọ nipa ọrọ naa ṣe ṣalaye fun ALAROYE, wọn ni lasiko ti ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun lọ fun itusilẹ ni ṣọọṣi naa ni wolii kona fun un pẹlu ẹtan pe ọmọ to wa ninu rẹ dabuu, oun si fẹẹ ba a ṣe e ti ọmọ naa yoo fi wa ni ipo to yẹ ko wa.
Gẹgẹ bi ọmọbinrin naa ṣe ṣalaye nigba to n royin ohun toju rẹ ri lasiko to lọ fun itusilẹ lọdọ Wolii Filani to wa loju ọna Ọda, niluu Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja.
Ọmọbìnrin to porukọ ara rẹ ni Bukọla ọhun ṣalaye fawọn oniroyin kan nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo ni olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro, Akurẹ, l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
‘‘Ọsibitu ni mo kọkọ ji lọ laaarọ ọjọ naa, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, lati lọọ forukọ silẹ fun ayẹwo orekoore oyun to wa ninu mi.
‘‘Bi wọn ṣe da mi lohun tan ni ọsibitu ni mo gba ṣọọsi wa lọ nitori pe o ni eto isin pataki kan ta a maa n ṣe ni gbogbo Ọjọruu, Wẹsidee.
‘‘O dun mi pupọ pe wọn ti pari isin ki n too de ṣọọsi, wolii wa nikan ni mo ba to ni ki n mu awọn nnkan ti wọn kọ fun mi lati ile-iwosan wa ki oun yẹ ẹ wo.
‘‘O fun mi pada lẹyin to wo o tan, o si ni ki n lọọ ṣe ẹda iwe ti wọn kọ awọn ẹru naa si, ki n si lọọ fi sori pẹpẹ to wa ninu sọọsi ki oun le gbadura si i.
‘‘Lẹyin eyi lo bẹrẹ si i fọwọ tẹ mi ni ikun nibi ta a jokoo si, o beere iye oṣu oyun to wa ninu mi, mo si sọ fun un pe oṣu marun-un ni.
O ṣeleri lati ṣe itusilẹ fun mi, leyii ti ma a fi bimọ wẹrẹ. Ko pẹ pupọ ni mo ri i ti wọn dide wọ inu yara to wa ninu sọọsi naa lọ, bi wọn ṣe wọle tan ni wọn pe mi pe kemi naa maa bọ.
‘‘Bi mo ṣe n wọle ni wọn ni ki n bọ aṣọ mi, ki n si dubulẹ, mo ṣaa ri i pe gbogbo nnkan ti wọn sọ fun mi ni mo n ṣe lai jiyan.
‘‘Ọkan ninu ika ọwọ wọn ni wọn kọkọ fi n ro idi mi daadaa, wọn ni awọn n ṣe bẹẹ nitori ọmọ inu mi to dabuu, wọn ni o ni ororo ti awọn yoo da soju ara mi, eyi ti awọn gbọdọ fi kinni abẹ awọn ti sọhun-un ki ọmọ naa le pada sipo to yẹ ko wa.
‘‘Lẹyin eyi ni wọn ni ki n la itan mi mejeeji, wọn ba mi lo pọ, wọn ni ṣe lawọn ran mi lọwọ nitori pe ohun ti ọkọ mi ti ko si nitosi yẹ ko ṣe fun mi lawọn n ṣe fun mi.
‘‘Ko si aṣọ adura lọrun wọn nigba ti wọn n ba mi sun, agbelebuu kekere kan ni wọn fun mi ki n fi sori idodo mi, wọn fun mi lomi adura mu, wọn si tun fin lọfinda si oju ara mi.
‘‘Gbogbo awọn nnkan wọnyi ni wọn ni yoo jẹ ki ọmọ inu mi pada sipo to yẹ ko wa.
‘‘Wọn ti ba mi sun tan ki oju mi too la, wọn ni ki n bura fun awọn pe mi o gbọdọ sọ fun ẹnikẹni nitori pe lọjọ ti mo ba ṣe bẹẹ ni ma a ku.
‘‘Wolii ọhun to tun jẹ ọkan ninu agba sọrọsọrọ nipinlẹ Ondo ṣi wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.