Jide Alabi
Wahala buruku lo n ṣẹlẹ laarin Sẹnetọ Rashidi Ladọja, gomina ipinlẹ Ọyọ, tẹlẹ lori bi Ọbasanjọ ṣe sọ pe iwa aimoore ẹ lo jẹ ki wọn yọ ọ nipo lọdun 2005
Ana Furaidee, ọjọ Ẹti ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọrọ kan, ohun to si sọ ni pe iwa alaimoore ti Rashidi Ladọja hu sawọn eeyan meji kan ti wọn ran an lọwọ to fi di gomina gan-an lo jẹ ki wọn yọ ọ danu nipo gomina.
Ọbasanjo ni ka ni ko huwa alaimoore si Oloye Lamidi Adedibu ati Alaaji Yẹkinni Adeọjọ ni, idaamu ti wọn ko ba a lori bi wọn ṣe yọ ọ nipo gomina Ọyọ lọdun 2005 ko ba ma ti ṣẹlẹ sí í.
Ọrọ yii ni Ladọja gbọ, n loun naa ba fun Ọbasanjọ lesi rẹpẹtẹ. Ninu alaye to ṣe lo ti sọ pe Ọbasanjọ gan-an ni eṣu lẹyin ibeji oun lori ọrọ naa, ohun to si fa a ni pe nitori ti oun ko ti i lẹyin lori bo ṣe tun fẹẹ ṣe aarẹ lẹẹkan si i, eyi ti yoo mu un lo saa mẹta lori ipo, lo da wahala silẹ laarin awọn.
Agbenusọ fun Ladọja nipa eto iroyin, Alaaji Lanre Latinwọ, sọ ọ lorukọ Oloye Rashidi Ladọja wi pe awuruju lasan ni igbesẹ tawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Ọyọ gbe nigba yẹn lori bi wọn ṣe yọ gomina naa nipo. O ni gbogbo ọrọ naa lo si ni ọwọ Ọbasanjo ninu, ṣugbọn niṣe lo lo awọn eeyan kan lati fi ṣe mọdaru ọhun.
O fi kun un pe ọrọ Ọbasanjọ ko le ya oun lẹnu rara nitori agba ti n de si baba naa, bẹẹ lo ṣee ṣe ko maa gbagbe ọpọlọpọ nnkan lasiko yii.
Ọkunrin oloṣelu ọmọ ilu Ibadan yii sọ pe, “Emi ti dari ji Ọbasanjọ o, nitori pe agbalagba ni, bẹẹ o ṣee ṣe ki agbalagba ma ranti awọn nnkan to ti ṣe tẹlẹ, ṣugbọn mo fẹẹ fi da gbogbo aye loju wi pe Ọbasanjọ lo wa nidii bi awọn aṣofin ṣe yọ mi nipo gomina ki ile-ẹjọ giga too da mi pada.
“Ṣe Ọbasanjọ gbagbe pe Adeọjọ to sọ pe oun lo ran mi lọwọ ti mo fi di gomina yii, a jọ figagbaga ninu ibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila ọdun 2002, ni Liberty Stadium, niluu Ibadan ni?
“Mo ranti daadaa wi pe nibi ọjọọbi Baba Emmanuel Alayande niluu Ibadan ninu oṣu kjeila ọdun 2005 ni Ọbasanjọ sọ ọ nibẹ wi pe ki wọn sọ fun Sẹnetọ Ladoja ko kọwe fipo gomina silẹ, ati pe ti mi o ba ṣe bẹẹ, niṣe lawọn aṣọfin yoo yọ mi nipo.
“Bo ti ṣe halẹ ̀ọhun niyẹn, nigba to si maa fi di bii ọjọ meloo kan si i, niṣe lawọn ọta ijọba dẹmokiresi to ran niṣẹ nipinlẹ Ọyọ ṣiṣẹ buruku to ran wọn. Bẹẹ la dupẹ lọwọ Ọlọrun ti ile-ẹjọ to ga julọ da mi pada. Ẹ sọ fun Ọbasanjọ daadaa, ko si bo ṣe le ṣe to, awọn ohun buruku to ti ṣe sẹyin lo n da a laamu bayii, bẹẹ ni ko le ri itan to fọwọ ara ẹ kọ yi pada. Iwa buruku to ti hu sẹyin yoo maa le e kiri ni.”