Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Zamfara nigba kan, to ti di sẹnetọ tuntun to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Iwọ-Oorun Zamfara bayii, Abdulaziz Yari, ti sọ pe iwa ifọbọ-lọ ni ati irẹjẹ patapata lo jẹ sawọn eeyan apa Ariwa orileede yii, bo ṣe jẹ pe agbegbe kan naa, iyẹn iha Guusu orileede yii ni gbogbo awọn olori ẹka ijọba mẹtẹẹta, ti Aarẹ, ti aṣofin ati ti eto idajọ, ti wa.
Yari, to sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lori eto ileeṣẹ Tẹlifiṣan Arise kan, lowurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, sọ pe lara idi toun ṣe ta ko ilana pinpin ipo olori ileegbimọ aṣofin agba ti ẹgbẹ oṣelu rẹ, All Progressives Congress, APC, ṣagbatẹru rẹ niyi, tori irẹjẹ ni eto naa pada waa bọ si.
Ẹ oo ranti pe Godwill Akpabio, gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ lati dupo olori awọn aṣofin apapọ, ọkunrin naa lo si wọle lọsẹ to kọja yii. Eyi si wa lara ohun to mu ki Yari kọwe ifẹhonu han si eto pinpin ipo oṣelu sawọn agbegbe kọọkan ti ẹgbẹ APC ṣe.
Ni lọwọlọwọ yii, Bọla Tinubu, Aarẹ ilẹ wa ati olori ẹka iṣejọba wa lati Eko, ti i ṣe agbegbe Guusu, Olukayọde Ariwoọla ti i ṣe adajọ agba ati olori ẹka eto idajọ wa lati ipinlẹ Ọyọ ti i ṣe agbegbe Guusu, bakan naa ni Godswill Akpabio, olori ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, iyẹn sẹneeti, wa lati ipinlẹ Akwa Ibom ti i ṣe iha Guusu bakan naa.
Ninu ọrọ rẹ, Yari sọ pe: “Lati ibẹrẹ pẹpẹ, ẹgbẹ APC ni aṣa kan lati maa fikunlukun daadaa, ki wọn ba Aarẹ sọrọ, ki wọn ba awọn ọmọọlegbimọ aṣofin sọrọ, ki awọn alẹnulọrọ gbogbo fero wero, tori eyi ki i ṣe ọrọ ẹgbẹ nikan, ọrọ iṣejọba ati ti orileede ni.
“Amọ wọn o ṣe bẹẹ lọtẹ yii, ohun ta a kan ri ni pe inu iweeroyin la ti n ka a pe wọn ti ṣepade meji kan, wọn si ti fẹnu ko lori awọn orukọ ta a gbọdọ ṣatilẹyin fun. Eyi o dara to rara, nitori gbogbo wọn kan le mu imọran wa ni, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin funra wọn nikan ni ofin orileede yii fun laṣẹ lati yan awọn adari wọn bo ba ṣe wu wọn. Ẹgbẹ le pin ipo sibi kan, amọ awọn aṣofin le lawọn o fara mọ ọn.
“O daa, ẹyin naa ẹ wo o, APC pin awọn ipo wọnyi, a si n bi wọn leere pe ori ipilẹ wo ni wọn fi pin in? Njẹ wọn tiẹ ro ti ilana pin-in’re la-a’re to wa ninu ofin ilẹ yii? Bawo ni aarẹ, adajọ agba ati alaga awọn aṣofin yoo ṣe wa lati ibikan naa?
Ọyọ ni adajọ agba ilẹ wa ti wa, Eko ni Tinubu ti wa, Akpabio si wa lati Akwa Ibom, nigba kan naa. Ẹ tun wo o, ẹni to kan lati gba ipo lọwọ adajọ agba yii, iha Guusu/Iwọ-Oorun loun naa tun ti jade.”
Yari ni eto to ni kọnu-n-kọhọ ninu ni bo ṣe wa yii, irẹjẹ lo si jẹ fawọn eeyan agbegbe Oke-Ọya orileede yii. O leyii nigba akọkọ ti iru nnkan bẹẹ yoo waye, ko si sohun ti ko le tidi rẹ yọ, to ba ya.