Jọkẹ Amọri
Iwadii to nipọn ti bẹrẹ lati mọ ohun to fa iku eeyan marun-un ninu mọlẹbi kan ṣoṣo lẹyin ti wọn jẹ suya tan, ti wọn si mu nnkan mimu eleso le e.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Abia tiṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, ti ni kawọn eeyan maa fi oju ṣọri, wọn ni aṣẹ ti lọ sọdọ awọn ẹka ijọba ti yoo ṣayẹwo ohun to ṣẹlẹ naa lati tete bẹrẹ iṣẹ lori ẹ.
Ṣe lọjọ Iṣẹgun naa, olori ile, Ọgbẹni Sunday Ogba, lọọ ra suya wale, ti oun pẹlu iyawo ati ọmọ wọn obinrin jẹ. Awọn ọmọ ọrẹ, Sunday to waa ba wọn ṣe ọlude paapaa jẹ ninu suya ati nnkan mimu naa, mẹrin lawọn ọmọde ọhun, awọn mẹrẹẹrin ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa lo si ku, pẹlu Sunday to ra Suya ọhun wale.
Iyawo Sunday, Abilekọ Jessy Ogba, ati ọmọ rẹ nikan ni wọn ko ku lẹyin ounjẹ naa.
Ki i ṣe pe nnkan kan ko ṣe awọn naa o, niṣe ni gbogbo awọn meje to jẹ ounjẹ yii bẹrẹ si i bi, ti wọn diwọ mọnu. Ko pẹ ti Sunday atawọn ọmọ ọrẹ ẹ mẹrẹẹrin fi di oloogbe, ọpẹlọpẹ itọju ti Jessy ati ọmọ rẹ ri gba lawọn ko fi ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ijọba ipinlẹ Abia lo sanwo itọju awọn mejeeji, bẹẹ ni wọn ko oku awọn marun-un to doloogbe lọ sile igbokuu-si, wọn si ni wọn yoo ṣayẹwo fun wọn.
Ọmọ ọdun mẹta, mẹsan-an, mẹwaa ati mejila lawọn ọmọ to ku naa. Baba wọn, Chibuzor Ikwunze, ṣalaye pe ọrẹ oun ati alajọgbe ọdun to ti pẹ ni Sunday, niṣe lo si pe oun lọjọ Iṣẹgun pe koun jẹ kawọn ọmọ waa ba idile oun ṣere, ko si ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ, o ni bo ṣe maa n ko wọn lọ sile rẹ ti yoo ṣaye fun wọn niyẹn.
Afi bi wọn ko ṣe ji saye mọ l’Ọjọruu, lẹyin ti wọn jẹ suya tan, toun si ṣe bẹẹ padanu ọmọ mẹrin lọjọ kan ṣoṣo.
Ọkunrin yii waa bẹ ijọba ipinlẹ Abia lati jọwọ, ba oun ṣayẹwo awọn oku yii, koun le mọ iru iku to pa wọn gan-an.