Faith Adebọla, Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti lawọn o ni i kaaarẹ titi tawọn fi maa mọ awọn amookunṣika to wa nidii oku ọmọbinrin tẹnikan o ti i mọ orukọ ẹ kan ti wọn ba ninu apoti aṣọ nitosi otẹẹli kan labule Adekunle, to wa lagbegbe Adeniyi Jones, n’Ikẹja, ipinlẹ Eko.
Aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni wọn lawọn aladuugbo ṣadeede ba apoti aṣọ kan, iru eyi tawọn arinrin-ajo maa n lo, ti wọn gbe e si kọna kan loju ọna naa.
Nigba ti wọn yẹ apoti naa wo, wọn ri i pe oku ọmọbinrin kan lo wa ninu ẹ, wọn ti ge lara awọn ẹya ara rẹ lọ, wọn si ti ṣe e yankanyankan.
Kia ni wọn ti kan sawọn ọlọpaa, awọn ọlọpaa teṣan Mancenter lo wa sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti bẹrẹ iwadii. A gbọ pe wọn ti pe awọn oṣiṣẹ ati ọga otẹẹli kan to wa nitosi ibi ti wọn gbe oku naa si, wọn si ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo ni teṣan wọn.
Ẹnikan to ba iweeroyin Vanguard sọrọ laṣiiri sọ pe oru mọju ọjọ Wẹsidee lawọn oṣika ẹda kan waa gbe oku ọmọbinrin naa sibẹ, ko sẹni to mọ pato bo ṣe de’bẹ, o lawọn kan ji, awọn si ri apoti aṣọ naa nibẹ ni.
O ni ko si geeti l’opopona naa, tori ọna to lọ si otẹẹli ti wọn forukọ bo laṣiiri yii ni.
O tun sọ p’awọn oṣiṣẹ ẹka eto ilera ipinlẹ Eko atawọn agbofinro ti waa palẹ oku ati apoti aṣọ naa mọ fun ayẹwo, ati igbesẹ to kan.