Faith Adebọla
Oludamọran pataki lori eto iroyin si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, Ọgbẹni Temitọpẹ Ajayi, ti bẹnu atẹ lu Igbakeji Olori orileede yii tẹlẹri, Alaaji Atiku Abubakar, fun bo ṣe tẹpẹlẹ mọ gbigba iwe-ẹri Tinubu jade ni Fasiti Chicago, (CSU), nilẹ Amẹrika, latari awọn iwadii ijinlẹ ati aṣiri kan to n wa. Ajayi ni iwa ti Atiku hu naa ko daa, ki i si ṣe eeyan daadaa rara.
Loju opo ayelujara tuita rẹ lọkunrin naa ti sọrọ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
Temitọpẹ kọ ọ sibẹ pe: “Ni temi o, ọrọ to wa nilẹ yii kọja boya Aarẹ Tinubu gboye jade ni Fasiti Chicago tabi ko ṣe bẹẹ. Ootọ to wa nibẹ ni pe Igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Atiku, ki i ṣe eku ire.
“Ko daa keeyan yẹpẹrẹ ọrẹ rẹ, tabi wọ ọ nilẹ ni gbangba bii iru eyi ti Atiku ṣe fun Aarẹ Tinubu yii, nitori ipo aye lasan, ati idije fun ipo aṣẹ.
“Tinubu ta a n sọrọ rẹ yii, ko sohun ti ko ṣe tan lati ran Atiku lọwọ sẹyin. Tinubu to daṣọ iyi bo Atiku, to tun pese ibugbe fun un lasiko ti Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati ẹgbẹ oṣelu PDP rẹ n na an lẹgba, ti wọn tun ja a sihooho nidii oṣelu lọdun 2007.
“Ko daa ki ọrẹ kan sọ ara ẹ di ‘aleni-ma-dẹyin’ gẹgẹ bawọn Ekiti ṣe maa n sọ ọ, bii iru eyi ti Atiku ṣe yii, ko sidii to fi yẹ bẹẹ.
O tun ni, “ki lo fẹẹ tidi itọpinpin atọkudorogbo yii jade gan-an? Imulẹ-mofo lasan ni”
Bẹẹ lọkunrin naa sọ.
Amọ loju-ẹṣẹ lawọn kan ti n fesi sọrọ ọhun. Bi wọn ṣe n sọ pe ni tododo, ko daa keeyan finu han ọrẹ, wọn ni o ti di meji ninu awọn ọrẹ imulẹ Tinubu bayii ti wọn tẹmbẹlu ẹ ni gbangba, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe iwa yiyiwee ati irọ pipa labẹ ofin ko daa rara.
Ẹ oo ranti pe lẹyẹ-o-sọka tawọn iwe-ẹri Aarẹ Bọla Tinubu ti tẹ Atiku lọwọ l’Amẹrika lawọn aṣiri kan ti bẹrẹ si i tu jade pe Tinubu yiwee, wọn lo ṣe ayederu iwe-ẹri Fasiti Chicago to lọ ni, bẹẹ lo parọ ileewe girama to lọ.
Bakan naa lo jẹ pe arọni o wale, Onikoyi o sinmi ogun i lọ ni Atiku fi ọrọ gbigba awọn iwe-ẹri naa ṣe ninu ẹjọ to pe l’Amẹrika, bẹẹ ni ko dẹyin lori arọwa tawọn kan pa fun un pe ko jawọ ninu wiwa fin-in idi koko sabukeeti Tinubu.