Iwọde Too-geeti: Ẹni to ba fẹẹ ja fun Naijiria gbọdọ mura lati fori la iku – Misita Macaroni

Ọkan pataki ninu awọn to foju wina ibinu awọn agbofinro lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu keji yii, lasiko iwọde tawọn ọdọ ṣe ta ko bijọba ṣe lawọn fẹẹ ṣi Too-geeti Lẹkki, nipinlẹ Eko, ni ilumọ-ọn-ka adẹrin-in poṣonu, to tun jẹ oṣere nni, Debọ Adedayọ, ti ọpọ eeyan mọ si Mista Makaroni (Mr. Macaroni). Lọjọ keji iṣẹlẹ yii, Debọ ba akọroyin ALAROYE, FAITH ADEBỌLA, sọrọ lori bi wọn ṣe mu un, ohun toju ẹ ri, o si tan imọlẹ si awọn awuyewuye kan.

Ẹ darukọ yin fawọn eeyan

Orukọ mi ni Adebọwale Adedayọ, ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Mr. Macaroni.

 Ki lohun to ṣẹlẹ gan-an nibi iwọde tẹẹ lọ?

Ni ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2021, mo lọ si Lẹkki Phase 1, nibi ti mo ti fẹẹ lọọ ya fidio kọmẹdi (comedy) kan tori awọn ololufẹ mi, ti mo fẹ ki wọn fi jẹgbadun ọdun falẹntain (Valentine) oni yii. Ṣugbọn mo tun mọ pe iwọde kan tawọn ọdọ fẹẹ ṣe maa waye, tori bi wọn ṣe lawọn o ti i fẹ kijọba ṣi too-geeti Lẹkki pada, nigba to jẹ pe awọn mọlẹbi awọn ti ṣọja pa, ati awọn to fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii lasiko ti iṣẹlẹ EndSARS ọdun to kọja ṣi wa ninu ẹdun ọkan, tijọba o si ti i ṣe nnkan kan fun wọn yatọ si ti ijokoo igbimọ ti wọn ti n gbọ aroye wọn. Iyẹn lawọn eeyan fi n sọ pe kijọba ma ti i ṣi Too-geeti yẹn. Ki n ma parọ, ẹru kọkọ ba emi funra mi nigba ti mo ri awọn ọlọpaa rẹpẹtẹ ti wọn dihamọra wamu-wamu ni Too-geeti laaarọ ọjọ yẹn, amọ bi mo ṣe wa ni Lẹkki Phase 1 yẹn, ọkan mi o gba a pe ki iru iwọde yẹn maa lọ nibẹ, ti mo si mọ pe ohunkohun lo le ṣẹlẹ sawọn ọmọ ọlọmọ, ni mo ba ni ki n tiẹ lọ si ibẹ, ki n lọọ wo nnkan to n ṣẹlẹ. Tẹẹ ba ri fidio ti mo kọkọ ju sori atẹ ayelujara, ẹ maa ri i pe ẹgbẹ kan ni mọ kọkọ rọra duro si, mi o sun mọ ibi ti wọn wa rara.

Ki n too mọ, awọn ọlọpaa kan ti waa ba mi, wọn ni kin ni mo n wa. Mo ni ṣe ẹṣẹ ni ki n wa nibi ti mo wa yii ni, wọn ni ko yẹ keeyan kan wa nibi lasiko yii, wọn ni ki n kuro, ni mo ba yipada, ṣugbọn ni gbogbo asiko yẹn, mo ti tan kamẹra foonu mi silẹ, gbogbo biṣẹlẹ yẹn ṣe n ṣẹlẹ ni mo n ya, tawọn ọlọpaa o mọ, ti mo si n sọ fawọn eeyan pe ‘ẹ wo ohun to n ṣẹlẹ o, awọn eeyan kan lo wa lọhun-un yẹn o, a o mọ ohun to n ṣẹlẹ si wọn o’.

Bawọn ọlọpaa kan tun ṣe waa ba mi niyẹn, wọn ni ọga awọn n pe mi, lọga wọn ba paṣẹ pe ki wọn lọọ ti mi mọnu mọto ti wọn fi n gbe awọn ọdaran (Black Maria), ni wọn ba wọ mi sinu mọto yẹn, ṣugbọn foonu mi ṣi wa lọwọ mi, to n ya fidio lọ.

Bi mo ṣe wọle, mo ba ọkunrin kan ninu mọto yẹn ti wọn ti kọkọ mu, Damilare lorukọ ẹ, o ni wọn ti mu oun lataarọ o, pe tori iwọde yẹn gan-an loun ṣe wa, pe ṣe mimu ti wọn waa mu wa yii lo kan. Bẹẹ ni mo n ju fidio bo ṣe n lọ sori ayelujara, kawọn aye le mọ ohun to n ṣẹlẹ.

Ko pẹ naa ni wọn tun mu awọn eeyan mẹta kan, ti wọn tun wọ wọn sinu mọto pẹlu wa.

 

Bẹ ẹ ṣe wa ninu mọto yẹn, njẹ wọn fiya kankan jẹ yin nibẹ?

Rara, wọn o tiẹ fiya jẹ wa o, gbogbo awọn ọlọpaa to wa ni Too-geeti yẹn o fọwọ kan wa yatọ si pe wọn kan ti wa mọnu mọto wọn nibẹ. 

 

Igba wo waa ni ọrọ ifiyajẹni, igbaju igbamu waa ṣẹlẹ?

Hẹn, mo ranti nnkan kan. Ni Too-geeti yẹn, nigba tawọn eeyan ti n ri awọn fidio ta a ju sori ayelujara, ti wọn ti n sọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ loriṣiiriṣii, boya awọn ọlọpaa naa gbọ nipa ẹ, ni wọn ba ranti pe awọn o ti i gba foonu lọwọ wa, wọn waa ba wa, wọn ni ka ko gbogbo foonu ọwọ wa wa, igba ti ẹnikan to wa lẹgbẹẹ mi o fẹẹ tete dahun, ọlọpaa kan da ẹṣẹ bo o, ni wọn ba gba foonu ọwọ wa. Ṣugbọn foonu meji lemi n lo, ko pẹ naa ni wọn tun pada wa, wọn lawọn fẹẹ yẹ ara wa wo, pe ta lo tun ṣi ni foonu lọwọ, mo ba tun yọ foonu mi keji jade, mo mu un fun wọn.

Ko ju iṣẹju meji si mẹta ti wọn gba foonu tan ni wọn ṣina ọkọ Black Maria ti wọn ko wa si, ni wọn ba n wa wa lọ. Wọn kọkọ wa wa lọọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Adeniji Adele, l’Ekoo. Ibẹ yẹn gan-an ni wọn ti fiya gidi jẹ wa.

Ba a ṣe n bọọlẹ ninu ọkọ ni tẹsan yẹn bayii, wọn ni ki gbogbo wa bọ aṣọ to wa lọrun wa, ni wọn ba bẹrẹ si i lu wa, wọn n gba wa loju, fun wa nipaa, wọn la kondo ọwọ wọn mọ wa lori, wọn tun n fun wa lẹṣẹẹ, oriṣiiriṣii iya ṣaa ni wọn n fi jẹ wa, wọn tun bẹrẹ si i ko bẹliiti (belt) wọn bo wa.

 

Ẹ to meloo nigba yẹn?

A jẹ bii mẹẹẹdogun nigba yẹn, iyẹn awa ta a kọkọ debẹ. Bẹẹ ni wọn ṣaa n lu wa. Oju buruku lo wa lagbari awọn ọlọpaa wọnyẹn, wọn ni awa la n da awọn laamu, awa la fẹẹ ya alagidi, abi? Wọn niṣe lawọn maa pa wa danu. Tawọn ba pa wa, ko sẹni to maa mọ, ko si sẹni to maa mu awọn si i.

Ẹni kan ninu wọn tiẹ sọ fun emi pe niṣe lawọn fẹẹ mu gende meji ti mi, tori emi ni wọn ni mo n ki awọn awọn eeyan laya lati ṣewọde. Wọn lawọn maa jẹ ki wọn lu mi pa ni, ti o ba jẹ pe awọn mu mi lojumọmọ ni, niṣe lawọn iba pa mi danu lọwọ kan.

Ṣugbọn wọn o ṣeyẹn o, ọkan ninu awọn ọlọpaa yẹn naa lo n sọ fun mi pe oun loun o gba pe ki wọn ṣe bẹẹ, tori oun o fẹ ki wọn paayan kan si teṣan toun wa.

Yatọ si lilu, o nigba kan ti wọn ni ki gbogbo wa bọ aṣọ ara wa, titi kan pata ta a wọ, wọn bọ wa sihooho goloto, wọn lawọn fẹẹ yẹ gbogbo ara wa wo, boya nnkan kan wa ta a fi pamọ sabẹ tabi bakan. Gbogbo wa pata la wa nihooho ibinbi ninu sẹẹli ti wọn ti wa mọ.

 

Ki lo n lọ lọkan yin nigba ti gbogbo eleyii n ṣẹlẹ?

Mi o le parọ, ẹru ba mi o, ẹru ba mi gidi gan-an. Ọrọ Naijiria waa gba omije loju mi, mo waa ri i pe ija yii, ija akinkanju ni. Amọ boya awọn ọlọpaa yẹn o mọ, niṣe ni gbogbo nnkan yẹn tun waa ki mi laya si i. Mo waa ṣẹṣẹ ri gbogbo ohun ti awọn baba wa kan ti ja fun nigba ti wọn n ja fẹtọọ wa, awọn baba wa bii Fẹla Kuti, Gani Fawẹhinmi ati bẹẹ bẹẹ lọ, mo waa n foju inu wo bi wọn ṣe n fiya jẹ wọn nigba yẹn. Ṣugbọn mo tun ro o pe gbogbo ẹ ko ju iku lọ, mo si mọ daju pe ki i ṣe pe mo huwa ọdaran kan, mi o gbebọn, mi o jale, ọrọ ilu naa lo ka mi lara ti mo si n tori ẹ jade pe bi wọn ṣe n ṣe yii, ko daa to.

Ṣaaju asiko yii, njẹ ẹ ti ni iru iriri bayii ri?

Irọ o, ko ṣẹlẹ si mi bayii ri. Loootọ o, ni gbogbo igba ti mo wa nileewe, mo maa n ba awọn eeyan ja fun ẹtọ ọmọọlewe o, iyẹn bii ka ṣe yuniọn tabi ka ṣewọde ALUTA awọn ọmọleewe fasiti nigba yẹn, ṣugbọn ko debi tawọn ọlọpaa maa ṣe mi bi wọn ṣe ṣe mi yii ri.

 

O fẹẹ jẹ pe ẹyin lẹ da bii ẹni to lorukọ ju lasiko iwọde eleyii yatọ si bo ṣe ṣẹlẹ lasiko iwọde EndSARS tawọn oṣere ẹlẹgbẹ yin mi-in jade. Ki lo mu keleyii ri bẹẹ?

Ẹ woo, ẹ ma jẹ n parọ fun yin o, a o le da ẹnikankan lẹbi o. Emi o si le da ẹnikẹni lẹbi, tori gbogbo wa pata la mọ ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ niluu lasiko yii. Ko si ibikita fun ẹmi ọmọ eeyan latọdọ ijọba rara ati rara ni. Ijọba le pa ẹ, to ba wu wọn, ti wọn si ro lọkan wọn pe ko si nnkan to le ṣẹṣẹ ti wọn ba ṣe bẹẹ. Ti wọn ba fẹẹ pa ẹnikan, wọn kan le purọ mọ ọn, ti wọn aa sọ pe awọn ri ibọn lọwọ ẹ, tabi pe awọn ka a mọ ibi kan ti o da, ko juyẹn lọ, wọn ti pa onitọhun sọnu niyẹn. Ṣe ẹ mọ pe mọ sọ pe ẹru kọkọ ba emi naa gidi, to jẹ niṣe ni mo kọkọ pẹlẹngọ sibi kan lati ya fidio. Tori ẹ, awọn ti wọn o jade, ki i ṣe ẹbi wọn, awọn naa o fẹẹ ku ni, ko sẹni to fẹẹ ku.

 

Ẹkọ wo ni ohun to ṣẹlẹ yii kọ ọ yin?

Ẹkọ ti mo kọ pọ diẹ o. Ẹkọ akọkọ ti mo kọ ni pe iwọ to o ba fẹẹ ja ija Naijiria, ni in lọkan ara ẹ pe o le ku, bẹẹ ni, o le ku si i. Ọlọrun waa le ṣe e o, keeyan ma ku o, ṣugbọn keeyan kọkọ ni i lọkan, ko si gba pe o le la iku lọ.

Ẹkọ mi-in ni pe iya maa jẹ oluwaẹ, wọn maa sọ oriṣiiriṣii ọrọkọrọ ati erokero si ẹni naa. Ọpọ awọn ọlọpaa to wa nibẹ lo n sọrọ si mi, wọn ni ṣebi awọn kan ti kowo fun mi ni, ṣebi awọn kan ran mi niṣẹ ni, laimọ pe ija tiwọn gan-an la n ja. Abi bawo la ṣe maa wa ninu ilu ta a maa maa ba ọlọpaa ja, ọlọpaa to yẹ ki wọn maa daabo bo wa, ki la tun fẹẹ maa ba wọn ja si. Emi o koriira ọlọpaa, mi o si ni wọn sinu, ṣugbọn awọn kan ti ba iṣẹ ọlọpaa jẹ, ijọba wa o si bikita rara, radarada ranun-ranun ni wọn n ba kiri, to fi jẹ pe lasiko yii, ko ti i si iru asiko ti eto aabo mẹhẹ bii eleyii ri, ti awọn Fulani darandaran maa maa paayan rẹkẹrẹkẹ, tijọba si maa ṣe bii ẹni ti ko ri wọn, toriṣiiriṣii aburu n ṣẹlẹ lọtun-un losi lojoojumọ, ta o dẹ gbọ kijọba tiẹ tara para rara.

Tori ẹ, wọn a tabuku ẹni to ba fẹẹ ja fun ilu, ṣugbọn lẹyin abuku yẹn, ogo lo maa tẹle e.

 

Awọn kan n fẹsun kan yin pe boya awọn kan lẹ n ṣiṣẹ fun, awọn kan tiẹ ni boya Atiku ni…

Atiku wo, Ha! Atiku, nibikibi too ba wa, o jẹ jade sọrọ. Inu ẹ tiẹ n bi mi, tori boun naa ṣe n gbọ awọn ẹsun irọ wọnyi to dẹ dakẹ, ti ko le sọ ootọ ibẹ sita. Wẹl, awọn to mọ emi, wọn mọ mi o, ẹ lọọ beere mi lọwọ awọn obi mi, ati kekere mi ni, tabi ki n sọ pe atigba ti mo ti gbọnju lo ti jẹ pe mi o le wa nibi ti ibajẹ kan ti n ṣẹlẹ ki n ma le sọrọ, ko ṣẹlẹ ri, ko mọ mi lara rara ni, ara temi o tiẹ le gba a. Latigba ti mo ti wa ni sẹkọndiri skuu (secondary school), ẹ lọọ beere. Wọn ti tori pe mo sọrọ pe awọn iwa kan o daa ko maa ṣẹlẹ nigba yẹn, wọn da mi duro nileewe, ti wọn sọspẹndi (suspend) mi, sibẹ iyẹn o ni ki n dakẹ o, wọn dẹ tun gba mi pada. Titi ti mo fi de yunifasiti, bẹẹ naa ni.

Ẹ lọọ wo awọn ọrọ ti mo kọ nipa Atiku nigba to loun fẹẹ ṣe purẹsidẹnti lọdun 2015, ẹ lọọ wo awọn nnkan ti mọ kọ nipa ẹ. Ṣe oju owo lo n pọn mi ni abi iya kan n jẹ mi bayii ni ti mo fi maa gba owo lọwọ Atiku tabi lọwọ ẹnikan, Ọlọrun ti kẹ mi, ko si nnkan ti mo n wa. Ija tara mi, ati ija tawọn eeyan lemi n ja.

 

Awọn kan ni boya Mista Makaroni fẹẹ wa kun orukọ ni

Orukọ wo, ṣe awọn eeyan o ti i mọ Mista Makaroni ni, ẹ ṣaa ti mọ ọn, ta ni o mọ mi ninu yin. Ṣe orukọ naa ni mo n wa ti wọn n gba mi lẹṣẹẹ, ti wọn n fun mi ni buloo (blow) loju nimu, abi ẹ o rii bi oju mi ṣe daranjẹ, ṣebi ẹ ri gbogbo ara mi, ṣe orukọ naa ni mo n wa ti wọn aa maa ja mi sihooho. Mo ro pori awọn to n sọ bẹẹ o tiẹ pe rara. Ọlọrun ti fun emi lorukọ o.

 

A tun gbọ pe nigba ti wọn tu u yin silẹ, ti wọn ni kẹ ẹ maa lọọ ile, ẹ taku pe afi ti wọn ba fi awọn to ku silẹ lẹ maa too lọ, ṣe loootọ ni?

Bẹẹ ni, ootọ ni. Ki lo de to fi jẹ pe Mista Macaroni ni wọn fẹẹ sare tu silẹ. Awọn to ku yẹn gan-an lakinkanju. Ẹ ti lu wa, ẹ ti ṣoriṣiiriṣii fun wa, ẹ waa fẹẹ sare femi nikan silẹ, ti mo ba kuro nibẹ, kin ni mo mọ ti wọn maa ṣe fawọn to ku? Ni mo ba ni rara, afi ti gbogbo eeyan ti wọn mu ba kuro nibẹ. Wọn tiẹ lawọn tun le ti mi mọle pada, mo dẹ ni o ti ya, mo fara mọ ọn ju pe ki n da nikan kuro nibẹ lọ. Igba ti wọn si fi gbogbo wa silẹ naa ni mo too lọọ sile.

 

Wọn ni ọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ (CID) ni Yaba ni wọn tun ko yin lọ ki wọn too tu yin silẹ

Bẹẹ ni, Adeniji yẹn, o da bii pe ile ti wọn ti n fiya buruku jẹ awọn eeyan niyẹn, awọn onroro ọlọpaa lo wa nibẹ, niṣe ni mo tiẹ n ro pe awọn ọlọpaa SARS ti wọn tu ka ni wọn ṣẹku sibẹ, tori tikanra-tikanra ni wọn lu wa. Ti CID yẹn, awọn tiẹ tun rọju diẹ, awọn yẹn tiẹ ṣe wa bii eeyan. Oju ọlọmọ-o-to ni Adeniji yẹn, wọn ṣetan lati paayan nibẹ yẹn, wọn o bikita rara.

 

Bii aja to re’le ẹkun to bọ, ki lẹ fẹẹ sọ bayii fawọn ọmọ Naijiria, awọn ọdọ ti wọn le tun fẹẹ ṣewọde atawọn ololufẹ yin gbogbo.

Loootọ, mi o si ni ipo lati sọ fẹnikẹni pe ọna bayii lo daa ju lati sọ erongba tabi ẹdun ọkan ẹ fun ijọba. Ibi to ba yẹ ki eeyan ti fẹhonu han, ọrọ sisọ le ma ṣiṣẹ nibẹ, onikaluku lo si maa pinnu bo ṣe maa sọ ero-ọkan ẹ jade. Ṣugbọn ni temi, ohun ti mo ba gbagbọ, ti mo si mọ pe o maa ṣiṣẹ lati jẹ ki ilu yii daa, mi o le dakẹ nipa ẹ. Mo si ni ọpọ awọn to n gba temi rẹpẹtẹ lori atẹ ayelujara ti mo mọ pe nnkan o dẹrun fun bo ṣe ri femi. Ki waa lanfaani ẹ temi ti wọn n fifẹ han si ba n gbe igbe aye irọrun, ṣugbọn ti awọn o rẹni gbeja wọn, ti wọn o rẹni gba ẹnu wọn sọrọ fun ijọba. Ti mo ba mọ pe igbesẹ kan maa ṣe wọn lanfaani, to maa jẹ ki ijọba mọ iya to n jẹ wọn, ma a ṣe bẹẹ, lai ka ohun ti mo ba ba pade nidii ẹ si.

Loootọ, mọ’ja-mọ’sa laye o, ki i si ṣe gbogbo ẹ naa ni iwọde, ṣugbọn ti gbogbo wa ba panu-pọ, ti a ba fohun ṣọkan, bii apẹẹrẹ, lasiko ibo to n bọ ni 2023, ti a ba wo ibi to yẹ ki a lọ, ẹni to yẹ ka le kuro, a le fi iṣọkan wa mu ayipada rere ba ilu yii o. A kan n ro pe o le ni, ti gbogbo wa ba pinnu, ti a si duro, a maa tun ilu yii ṣe.

 

Ki lawọn nnkan tẹ ẹ padanu latari iṣẹlẹ yii?

Akọkọ, ṣe ẹ ri i pe wọn ti ba fain bọi mi jẹ bayii, abi ẹ o ri i. Mista Makaroni fain ju bayii lọ tẹlẹ nao (gbogbo wa rẹrin-in).

Bi mo tun ṣe n kuro nibi yii, ọsibitu ni mo n gba lọ, lati lọọ ṣayẹwo ara mi, ki n si tọju ara mi. Ẹ tun wo foonu mi mejeeji ti wọn fọ. Ọlọpaa yẹn diidi fibinu fibọn ọwọ ẹ fọ gilaasi ẹ ni nigba ti wọn ni ko da a pada fun mi. Mo mọ pe wọn diidi fẹẹ fiyẹn ṣeruba awọn eeyan ni, ki wọn le maa ro pe ta a ba le ṣe bayii fun Mista Macaroni, ko sẹni ta o le ṣe ju bẹẹ lọ fun, ṣugbọn irọ ni, gbogbo bo ṣe n lọ lo ye wa.

Ki lero yin nipa igbimọ tijọba gbe kalẹ lati wadii awọn ẹsun ta ko SARS, ati bawọn ọdọ ati lọọya Adegboruwa ṣe lawọn maa kuro ninu igbimọ ọhun?

Wọn maa kuro kẹ, ko si bi oloootọ eeyan ko ṣe ni i kuro nibi ti wọn ba ti n dana irọ. Igbimọ yẹn, igbimọ ọtẹ ni. Igbimọ to ti jokoo fun bii oṣu mẹta-mẹrin to jẹ ẹjọ oriṣiiriṣii la n gbọ, ko si koko gidi kan. Ko si ifiyajẹni fun awọn ọlọpaa ti wọn fẹsun kan, ko si iranwọ kan fawọn ti wọn fiya jẹ lai tọ tabi ti wọn tẹ ẹtọ mọ mọlẹ.

Ẹ dahun, ṣe to ba jẹ ọmọ eeyan nla kan, tabi oloṣelu nla kan l’Ekoo ni wọn pa ọmọ tiẹ ninu iwọde EndSARS ọjọ yẹn, ṣe wọn aa ti i ronu kan ṣiṣi too-geeti yii? Ohun ti a n sọ niyẹn.

 

Leave a Reply