Faith Adebọla
Agbarijọ ẹgbẹ awọn ajijagbara ti wọn n ja fun yiya kuro lara orileede Naijiria, ti wọn lawọn fẹẹ da duro, ti mu ileri wọn ṣẹ pẹlu bi wọn ṣe bẹrẹ iwọde ni olu-ile Ajọ Iṣọkan Agbaye, lorileede Amẹrika.
Iwọde naa, eyi ti ẹgbẹ NINAS, to ko gbogbo awọn ẹgbẹ to n ja fun ominira orileede wọn kuro lara Naijiria, iyẹn Nigerian Indigenious Nationalities Alliance for Self-Determination, ṣagbatẹru ẹ, waye ninu agbala ile ẹgbẹ Iṣọkan Agbaye naa, ọpọ ero lati Naijiria, Amẹrika ati awọn orileede mi-in la gbọ pe o darapọ mọ iwọde ọhun.
Lara awọn to wa nibi iwọde naa ni awọn to n ja fun idasilẹ orileede ‘Yoruba Nation’, eyi ti Ọjọgbọn Banji Akintoye ṣaaju wọn, awọn to n ja fun idasilẹ orileede ‘Biafra’ eyi ti ẹgbẹ IPOB n polongo, ati awọn eeyan agbegbe Guusu ati Aarin-Gbungbun Naijiria.
Oriṣiiriṣii akọle fẹrẹgẹdẹ ni wọn gbe dani, lara awọn ọrọ ti wọn kọ lede eebo sara akọle naa ni: “Ẹ ran wa lọwọ lati fopin si Naijiria ka ma baa ku tan,” “A o le dakẹ mọ o, a ti n sọrọ soke,” “miliọnu kan ọmọ Naijiria lo ṣoju fawọn to wa nile o, a o fẹ Naijiria mọ” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn mi-in gbe aworan ati akọle ẹgbẹ IPOB dani, nigba ti ti “Yoruba Nation” tabi “Orileede Oduduwa” wa lọwọ awọn kan. Wọn lohun tawọn n fẹ ni ki Ajọ Iṣọkan Agbaye waa ba awọn mojuto eto iwadii ati ilana bi Naijiria ṣe maa pin nirọrun, ti kaluku yoo gba ile rẹ lọ.
Ba a ṣe gbọ, gbogbo ọjọ ti ipade Iṣọkan Agbaye naa yoo fi waye ni wọn lawọn oluṣewọde yii yoo fi maa sọ erongba wọn di mimọ, wọn nireti wa pe ọpọ ero yoo tun darapọ mọ wọn bi wọn ṣe n tẹsiwaju.