Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Ayọtọmiwa Ẹlẹgbẹlẹyẹ, ti kegbajare lọ siwaju igbimọ oluwadii to n gbọ ẹjọ ifiyajẹni lọwọ ikọ SARS atawọn iṣẹlẹ mi-in lasiko iwọde SARS, nibi to ti ni awọn SARS lo ko ba oun, oun ki i ṣe adigunjale.
Ọkunrin ti wọn mu wa lati ọgba ẹwọn naa sọ pe ẹṣẹ aimọdi loun n jiya ẹ lọwọlọwọ nitori ṣe lawọn SARS kan deede waa ka oun mọle ni nnkan bii aago mejila oru ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, niluu Ikẹrẹ-Ekiti, ti wọn si wọ oun lọ si agọ ọlọpaa.
O ni wọn fi irin kan so oun mọ oke, wọn si fi ẹrọ ilọṣọ da bataani soun lara fun ọjọ mẹtalelogun gbako, bẹẹ ni wọn ni koun mu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) wa toun baa fẹẹ gba itusilẹ.
Ayọtọmiwa ni, ‘‘Ile mi ni wọn ti waa mu mi. Lalẹ ọjọ yẹn, wọn mu mi lọ si ọfiisi wọn, nibẹ ni wọn ti fi ẹrọ ilọṣọ fiya jẹ mi, ti wọn ni ki n sọ pe adigunjale ni mi.
‘‘Eemi mi ko ja gaara, mo ṣaa n bẹ wọn ki wọn fi mi silẹ, ṣugbọn wọn ni awọn gbọdọ gba owo yẹn.
‘‘Lẹyin ọjọ mẹtalelogun ti mo ti fara pa yannayanna ni wọn gbe mi lọ si ọsibitu awọn ọlọpaa to wa ni Okeṣa, niluu Ado-Ekiti, nitori wọn ro pe mo maa ku.’’
Ọkunrin naa waa bẹ igbimọ oluwadii ọhun lati ṣewadii ijinlẹ, ki wọn le yọ alaiṣẹ ninu ajaga ọgba ẹwọn.
Ninu esi agbẹjọro ileeṣẹ ọlọpaa, o ni ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, ipaniyan ati idigunjale wa lọrun ọkunrin naa nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ekiti, ṣugbọn Amofin Layi Obiṣẹsan to duro fun un sọ pe o lẹtọọ lati pẹjọ lori iya tawọn SARS fi jẹ ẹ.
Ọjọ kẹta, oṣu to n bọ, ni ẹjọ naa yoo tun tẹsaiwaju kawọn ẹlẹrii le waa sọrọ fun igun mejeeji.