Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Isinmi ni obinrin kan to doloogbe ninu ijamba ọkọ pẹlu awọn ọmọbinrin ẹ meji fẹẹ lọọ lo nilẹ Ibo, eyi ni wọn fi bọ sọna, ti wọn n tirafu jẹẹjẹ ninu mọto ayọkẹlẹ jiipu wọn, iyẹn lọjọ keji ọdun Keresimesi yii. Afi bi ijamba mọto ṣe ṣẹlẹ nigba ti wọn de Ijẹbu-Ifẹ, nibi ileepo MRS atijọ, Itako, loju ọna marosẹ Ṣagamu si Benin, ti iya atawọn ọmọ ẹ mejeeji si ṣe bẹẹ dero ọrun.
Alaye ti Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe lori iṣẹlẹ yii ni pe obinrin to doloogbe yii pẹlu awọn ọmọ rẹ meji ati dẹrẹba to n wa wọn ni wọn jọ wa ninu mọto ayọkẹlẹ jiipu ti nọmba ẹ jẹ AKD 311 HH. Eko ni wọn ti kuro, ilẹ Ibo ni wọn si n lọ. O ni ṣugbọn awọn eeyan tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ere ti dẹrẹba to n wa iya atawọn ọmọ ẹ naa n sa pọ ju, bo ṣe lọọ rọ lu tirela ti nọmba ẹ jẹ WW 630 XA, ti wọn paaki silẹ jẹẹjẹ niyẹn, nigba naa ni ijamba nla ṣẹlẹ, ti awọn eeyan inu jiipu dero ilẹẹlẹ loju popo, iyẹn iya atawọn ọmọbinrin rẹ mejeeji yii, ni wọn ba ṣe bẹẹ dagbere faye laago mejila aabọ ọsan.
Kinni kan ko si waa ṣe dẹrẹba to wa wọn ti wọn fi ku yii, wọn ti fa a fọlọpaa gẹgẹ ba a ṣe gbọ ṣa, o si ti wa lakolo wọn.
Ilu oyinbo lọkọ obinrin to doloogbe naa wa, dẹrẹba to wa wọn pa yii ni wọn si gba bii dẹrẹba mọlẹbi wọn.
TRACE kilọ fawọn onimọto, gẹgẹ bi FRSC pẹlu ko ṣe yee wi, pe ati onimọto ero ati ti adani, ki wọn maa ro ti ẹmi ti ko laarọ, to jẹ to ba ti ja, o ja ni.