Florence Babaṣọla
Iyaale ile kan, Patience Ayube, ẹni ọdun mejilelaadọta, ati ọmọ rẹ, Josiah Ayube, to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogun, lawọn ọlọpaa ti wọ lọ si kootu Majisreeti kan niluu Ileefẹ lori ẹsun ole jija.
Yatọ si iya atọmọ rẹ yii, ọwọ tun tẹ Oluwaṣeun Joseph, ẹni ọdun mejilelogun ati Friday Emmanuel, ẹni ogun ọdun, lori ẹsun kan naa.
Ọkada Honda Motorcycle ti owo rẹ din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-un naira [N285, 000] ni agbefọba, ASP Abdullahi Emmanuel, sọ pe awọn olujẹjọ mẹrẹẹrin ji.
Agbefọba ṣalaye pe lagbegbe Texaco, niluu Ileefẹ, ni wọn ti ji ọkada naa, eyi to jẹ ti Ọgbẹni Emmanuel Akpan, to ni nọmba EKY 533 QM, ti wọn si tun huwa to le da omi alaafia agbegbe naa ru.
O ni iwa ti wọn hu naa lodi, bẹẹ lo si nijiya nla labẹ ipin irinwo o din mẹwaa ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Ọlalekan Babatunde, rọ adajọ lati fun un ni beeli lọna ti ko gunpa, pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.
Majisreeti A. I. Oyebadejọ fun olujẹjọ kọọkan ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira [N50,000] ati oniduuro kọọkan ni iye kan naa.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọgbọnjọ, oṣu kẹfa, ọdun yii.