Faith Adebọla
Afurasi ọdaran ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Afeez Ọlalere, ti jẹwọ pe oun loun pa aburo oun, o ni iya oun lo ni koun kuku lo o fun oogun owo toun fẹẹ ṣe.
Ni teṣan ọlọpaa Ikorodu lọkunrin naa ti ṣalaye ara ẹ, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lẹyin to ti ko sakolo awọn ọlọpaa ti wọn mu un nirona, laduugbo Itamaga, Ikorodu, nipinlẹ Eko, nigba ti wọn n yẹ ọkọ rẹ wo.
Afeez ṣalaye pe majele loun fun aburo oun ẹni ọdun mọkanlelogun mu, ko si ju bii ogun iṣẹju lẹyin to mu un tan lo ku.
O ni bo ṣe ku tan lawọn yọ ọbẹ ti oku aburo oun, wọn bẹrẹ si i ge awọn ẹya ara ẹ kan ti babalawo ti sọ pe ki wọn mu wa fun oogun owo ti wọn fẹẹ ṣe, awọn si palẹ iyooku oku naa mọ, awọn gbe e lọ si mọṣuari ileewosan kan, awọn si purọ fun wọn pe awọn ajinigbe afeeyan ṣetutu ni wọn pa a.
“Babalawo sọ fun wa pe awọn ẹya ara eeyan toun maa fi ba wa ṣoogun owo ni atampako, irun ori, awọn ọmọọka ọwọ ati ẹsẹ ati fọto pelebe ẹ kan. Emi ati iya mi lo sọ fun.
‘‘Nigba ta a dele, a ronu lori ẹ, mama mi si sọ pe ka lo aburo mi to jẹ ọmọọdun mọkanlelogun.
Mama mi gan-an lo ra majele ta a fi pa a, inu ounjẹ la fi si fun un, bo ṣe jẹ ẹ tan lo ku, lẹyin ogun iṣẹju, a si bẹrẹ si i ge ẹya ara ẹ ti babalawo ni ka mu wa.” Bẹẹ lafurasi ọdaran naa ṣalaye lagọọ ọlọpaa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajiṣebutu, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Wọn ti wa babalawo naa lọ sile ẹ, ṣugbọn wọn ko ti i ri i mu.
Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, AIG Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn taari Afeez sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, fun iṣẹ iwadii to lọọrin.