Adewale adeoye
Ilu ti ko ba sofin, ẹṣẹ ko si nibẹ, bi ofin ba ti de, ohunkohun ti tọhun ba ṣe to lodi sofin, ẹṣẹ ni, ti tọhun yoo si gba ijiya rẹ. Ni bayii, o ti di eewọ fawọn banki ilẹ wa lati maa ta owo Naira tuntun fawọn alaarobọ ti wọn n ra a lọwọ wọn, ti wọn n tun un ta fawọn araalu gbogbo lowo gọbọi.
Banki apapọ orileede yii, iyẹn ‘Central Bank of Nigeria (CBN), lo sọrọ naa di mimọ pe ijiya nla lo wa fawọn banki tabi oṣiṣẹ awọn Banki gbogbo tawọn ba fọwọ ofin mu pe wọn n ta awọn owo Naira tuntun fawọn alaarobọ ti won n tun un ta fawọn araalu. Miliọnu lọna aadọjọ Naira (150M) lowo itanran ti irufẹ banki bẹẹ maa san fun ijọba apapo bi wọn ba mu wọn.
Ọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun yii, ni Mohamed Ọlayemi, ti i ṣe ọga agba lẹka to n mojuto awọn ohun to n lọ ni banki naa lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni kinni ọhun ti fẹẹ di baraku fawọn ọbayejẹ ẹda kan lorileede yii pe ki wọn maa ta owo Naira tuntun fawọn alaarobọ ti wọn n tun un ta fawọn araalu. O ni wọn ti sọ ọ di okoowo gidi laarin ara wọn, ọrọ naa si ti de setiigbọ awọn nileeṣẹ banki apapọ orileede yii.
O ni igbesẹ gidi tawọn n gbe lori ọrọ naa ni pe banki yoowu lorileede yii tọwọ ba tẹ pe wọn n ta awọn owo Naira tuntun fawọn alaarobọ ti wọn n tun un ta fawọn araalu maa jiya gidi ni, miliọnu lọna aadọjọ Naira (150M) lowo ta a maa gba lọwọ awọn alaṣẹ banki naa gẹgẹ bii owo itanran fohun ti wọn ṣe, eyi si maa jẹ ẹko nla fawọn yooku.
Lati le ri i pe awọn banki gbogbo lorileede yii tẹle aṣẹ ati ilana to rọ mọ ofin iṣẹ wọn, wọn lawọn aa maa lọọ kaakiri aarin ilu lati wo bawọn banki kọọkan ṣe n ṣe pẹlu owo Naira naa, ati pe awọn yoo da awọn alami sita lọpọ yanturu lati fọwọ ofin mu awọn ọbayejẹ ẹda ti wọn n ta awọn owo tuntun fawọn alaarobọ naa.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti sọ pe, ‘‘O ti de setiigbọ wa pe awọn ọbayejẹ ẹda kan n ta awọn owo Naira tuntun fawọn alaarobọ ti wọn n tun un ta fawọn araalu. Ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe bẹẹ. A maa too bẹrẹ si i ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ta a si maa fiya nla jẹ awọn banki to ba lẹdi apo pẹlu awọn alaarobọ naa’’.
Banki apapọ orileede yii waa rọ awọn alaṣẹ banki gbogbo pe ki wọn ri i daju pe awọn ọbayejẹ ẹda to wa lọdọ wọn ko ko wọn sinu iyọnu, ki wọn si ṣeto wọn lọna igbalode tawọn oṣiṣẹ wọn ko fi ni i maa ta awọn owo Naira tuntun ọhun faraalu.