Iya ọna meji jẹ Awoniyi: Lasiko to wa latimọle ni iya ati iyawo rẹ ku, adajọ tun ju u sẹwọn ọdun mẹrinla l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ẹsẹ ko gbero nile ẹjọ to n ri si lilo ọmọde ni ilokulo atawọn iwa ọdaran mi-in ‘Special Offences Court’, to wa ni Ikẹja, nipinlẹ Eko, nibi ti igbẹjọ ti waye lori Ọgbẹni Samsondeen Awoniyi tawọn tawọn agbefọba ipinlẹ Eko fẹsun kan pe o fipa b’ọmọ ọdun mẹrinla kan ti wọn jọ n gbe laduugbo kan naa lagbegbe Ijesha-Tẹdo sun lọdun 2017, eyi ti Onidaajọ  Ramon Oshodi to n gbọ ẹjọ naa sọ pe o lodi sofin ipinlẹ Eko, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.

Nigba ti Agbefọba n ṣalaye niwaju Adajọ Oshodi, o ni, ‘Nibi tọrọ naa ti bẹrẹ ni awọn iṣẹ pẹpẹpẹẹ ti olupẹjọ maa n ra ọmọ ọdun mẹrinla naa, ti ọmọ naa si maa n jiṣẹ ti ọkunrin yii ba ti ran an.

Ṣugbọn Samsondeen ko fi mọ ni iṣẹ to n ran ọmọ yii, niṣe lo wo sunsun lọjọ kan, to si ki ọmọ naa mọlẹ, lo ba fipa ba a lo pọ lọdun 2017. Aṣiri iwa ti ko bofin mu yii pada tu, n lawọn obi ọmọ naa ba f’ọlọpaa mu un. Awọn agbofinro mu ọmọ naa lọ sileewosan lati ṣe ayẹwo fun un ki wọn le footọ to wa nidii ọrọ naa mulẹ, esi ayẹwo tawọn dokita ṣe si fi han gbangba pe ootọ ni olujẹjọ huwa naa. Atimọle ọgba ẹwọn lo gba de kootu, latigba naa ni wọn si ti wa lẹnu ẹjọ ọhun ko too di pe idajọ waye ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.

Ninu ọrọ lọọya olujẹjọ, o rọ adajọ ile-ẹjọ ọhun pe ko siju aanu wo onibaara oun lori ẹjọ to wa niwaju rẹ. O ni, ‘‘Oluwa mi, onibaara mi, Ọgbẹni Samsondeen Awoniyi, paapaa ti gba pe aṣiṣe nla gbaa lohun toun ṣe pẹlu ọmọ naa. Lasiko ti onibaara mi n jẹjọ lọwọ lo padanu iyawo ati mama rẹ, inu ahaamọ to wa ni iroyin iku awọn eeyan meji to nifẹẹ si ju lọ yii ti kan an, ko lanfaani lati waa wo wọn, bẹẹ ni ko si nibẹ lasiko ti wọn n ṣeto isinku wọn.

Niṣe ni olujẹjọ naa dọbalẹ korobata niwaju adajọ, to si n sọrọ taanu-taanu pe, ‘‘Oluwa mi, mi o mọ pe ibi ta a ja si fun mi ree, abamọ nla gbaa ni mo ke nigbẹyin ọrọ naa, kẹ ẹ si maa wo, lori ẹjọ yii ni iyawo ile mi ati iya mi ku si, mi o si nibẹ lasiko ti wọn n ṣeto isinku wọn’’.

Olujẹjọ loun tọrọ aforiji lọwọ adajọ ile-ẹjọ ọhun, ṣugbọn loju-ẹsẹ ni Onidaajọ Oshodi ti ni ki i ṣe lọwọ oun lo ti maa tọrọ aforiji rara, o ni ko kọju sawọn mọlẹbi ọmọ to fipa ba sun, ko tọrọ aforiji lọwọ wọn. Niṣe ni olujẹjọ gboju soke, ti omije si bẹrẹ si i da loju rẹ poroporo, to si n fi tẹkun-tomije bẹ awọn mọlẹbi ọmọ to ṣe ṣikaṣika naa pe ki wọn ṣaforiji f’oun, ṣugbọn awọn yẹn ko tiẹ da a loun, wọn kan n wo o ni tiwọn ni.

Beeyan ba ju abẹrẹ silẹ ninu kootu ọhun, yoo dun, nitori niṣe ni kootu naa parọrọ lasiko ti adajọ fẹẹ gbe ipinnu rẹ kalẹ. Asiko naa ni olujẹjọ bẹrẹ si i mi gulegule, ti oogun buruku si n bọ lara rẹ ni koṣe koṣe nitori ti ko mọ ibi gan-an ti igi idajọ naa maa wo si. Bẹẹ ni lọọya rẹ n ki i laya pe didun lọsan yoo so. Ohun to mu ki lọọya olujẹjọ sọ bẹẹ ni pe adajọ ti ni ko tọrọ aforiji lọwọ awọn ẹbi ọmọ to fipa ba sun, ati pe lori ẹjọ naa ni olujẹjọ tun padanu eeyan meji to nifẹẹ si ju lọ nigbesi aye rẹ si, eyi ni ọkunrin naa fi ro pe Onidaajọ Oshodi yoo ṣiju aanu wo o.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bawọn mejeeji ṣe ro o nigba ti adajọ kede pe oun ran an lẹwọn ọdun mẹrinla pẹlu iṣẹ aṣekara. O ni ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri. Bakan naa lo ni ki wọn kọ orukọ rẹ sinu iwe itan ipinlẹ Eko pe ọdaran paraku ni.

Ṣa o, adajọ ni ki wọn yọ iye ọdun ati oṣu ti olujẹjọ ti wa lahaamọ ijọba ipinlẹ Eko kuro ninu ọdun to maa lo lọgba ẹwọn.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori idajọ naa, agbẹjọro olujẹjọ ti ko gba ki akọroyin wa foju rẹ hande sọ pe oun fara mọ idajọ naa, ati pe olujẹjọ funra rẹ ti gba pe oun jẹbi, to si ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ẹbi ọmọ to fipa ba sun niwaju gbogbo eeyan, o ni awọn ko ni i pẹ ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kankan mọ lori idajọ ọhun.

Leave a Reply