Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ilu Apọnmu-Lọna, nijọba ibilẹ Idanre, ni pe iya ẹni ọdun mẹtalelaaadọrin to dana sun ọmọ bibi inu ẹ, Victor Ọlọrọ, iyawo rẹ, Rachael Ọlọrọ atawọn ọmọ wọn meji ti jade laye.
Iya agbalagba ọhun, Iforiti Ọlọrọ, ni wọn lo ku sile-iwosan ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ, nibi to ti n gba itọju lopin ọsẹ to kọja.
Iforiti funra rẹ fara pa yannayanna lasiko to n dana sun awọn mọlẹbi ọhun ninu ile ti wọn jọ n gbe lagbegbe Ẹyin-Odo, l’Apọnmu, loru ọjọ Abamẹta, Satide ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Gbogbo aya rẹ ati ọwọ rẹ mejeeji ni ina jo, dipo kawọn ọmọ rẹ sí gbe e lọ si ọsibitu fun itọju, ṣe ni wọn fi oun nikan silẹ sinu ile ọhun laarin asiko ti wọn fi ko Victor, iyawo atawọn ọmọ rẹ meji lọ sile-iwosan.
Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ni iroyin kan kaakiri pe Victor ati Rachael, iyawo rẹ ti ku si ọsibitu ijọba apapọ Ọwọ, ti wọn ti n gba itọju.
Bi ilẹ ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde, ṣe n mọ ni wọn ni akọbi mama naa lọkunrin pada wa si Apọnmu, pẹlu ibinu, to si ti gbogbo ilẹkun ile naa pa mọ iya wọn, koda, ṣe lo tun fi iṣo kan fereṣe yara ti obinrin ọhun wa pa ko ma baa tun lanfaani ati dana ijamba mi-in mọ.
Ariwo awọn eeyan ilu ọhun lo pọ ki ọmọkunrin ọhun atawọn ọlọpaa kan lati olu ileesẹ wọn l’Akurẹ too waa gbe e kuro ninu ile naa lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja lọhun-un.
Ohun ta a gbọ nigba naa ni pe ile-iwosan ijọba apapo, nibi ti wọn ko awọn mẹrẹẹrin to dana sun lọ ni wọn gbe oun naa lọ fun itọju.
Tẹ o ba gbagbe, sadeede ni obinrin naa bu bẹntiroolu sinu iha, to si ju u sinu ile ti ọmọ rẹ ọkunrin atiyawo pẹlu awọn ọmọ wọn mejeeji jọ n gbe.
Ina naa lo ṣe ọsẹ buruku lara tọkọ-tiyawo naa ti wọn fi pada ku sọsibitu ti wọn ti n tọju wọn.
Ṣugbọn awọn ọmọ mejeeji ṣi n gbatọju lọwọ lọsibitu.
Wọn ni iya agba yii sọ pe iyawo ọmọ oun loun fẹẹ kọ lọgbọn, oun ko ni i lọkan lati pa ọmọ oun tabi awon ọmọọmọ oun.
Nigba ti wọn beere ohun ti iyawo ọmọ rẹ yii ṣe fun un, o ni gbogbo ọja ti oun n ta ni ọmọbinrin naa ti gba mọ oun lọwọ, toun naa ti bẹrẹ si i ta iru rẹ.