Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Arọọda ojo kan to rọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, titi di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lo ṣokunfa ijamba ile wiwo lagbegbe Pakata ati Kankatu, si Okelele. Iyaagba kan ku, awọn ọmọde mẹrin fara pa, bakan naa ni dukia aimọye miliọnu Naira ṣofo nibi iṣẹlẹ naa.
ALAROYE lasiko ti ojo naa n rọ ti ko mọwọ duro ni ile ti iya naa n gbe da wo, to si ṣeku pa a.
Ileewosan aladaani kan ti orukọ rẹ n jẹ Fatima, lagbegbe Alagbado, Okelele, ni wọn ko awọn ọmọde to fara pa naa lọ fun itọju to peye, ti ara wọn si ti n ya bayii.
Bakan naa ni biriiji meji lo ja lulẹ, ọkan ja l’Opopona Kulende Harmony Estate si Akerebiata, nigba ti ikeji ja ni agbegbe Medina si Technical, Ọlọjẹ, latari ọpọ ojo. Bakan naa ni ojo naa ba ọpọ ile jẹ, o tun wọ awọn ẹja ti wọn n sin lọ.
Ijọba ipinlẹ Kwara ti kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn to fara kaasa ijamba naa. Ninu atẹjade kan ti kọmiṣanna to n ri si ọrọ ayika, Arabinrin Rẹmilẹkun Banigbe, ati Kọmisanna to n ri si ọrọ iṣẹ nipinlẹ naa, Onimọ ẹrọ Rotimi Iliasu, jọ buwọ lu ni wọn ti kẹdun pẹlu gbogbo awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ buruku ọhun, ti wọn si jẹjẹẹ pe ijọba yoo tete ṣe atunse si biriiji to ja, bakan naa ni wọn rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati ta kete si dida idọti si oju agbara.