Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti fidi ẹ mulẹ pe gbara tawọn ba ti pari iwadii lori iwa apaayan ti wọn fẹsun rẹ kan Abilekọ ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Maimunatu Sulaiman, ti wọn lo fibinu gun ọkọ ẹ, Aliyu Mohammad, lọbẹ nigbaaya, tọkunrin naa si ṣe bẹẹ dẹni akọlẹbo, lawọn maa taari ẹ siwaju adajọ ni kootu, ko le lọọ gba ijiya ẹṣẹ rẹ lẹkun-un-rẹrẹ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Aminu Gimba Ahmed, to fiṣẹlẹ ọhun ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun yii, sọ pe Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun 2023, niṣẹlẹ ibanujẹ naa waye nile ti tọkọ-tiyawo naa n gbe lagbegbe Kofar Dumi, nipinlẹ Bauchi.
O lawọn aladuugbo ni wọn kegbajare sileeṣẹ ọlọpaa lori aago wọn pe wahala kan ti tun ṣẹlẹ, ẹnikan ti gun ọkọ ẹ lọbẹ, kawọn tete maa sare bọ o, n lawọn ba tamọra, tawọn si de ibi ti wọn juwe ọhun, amọ o ya ni lẹnu pe inu agbara ẹjẹ lawọn ba baale ile naa, to ti n pọkaka iku gidigidi.
Eyi lo mu kawọn tete gbe e lọ sileewosan Abubakar Tafawa Balewa Teaching Hospital (ATBUTH), to wa niluu Bauchi, awọn si gbe iyawo rẹ naa lọ soṣibitu ọhun pẹlu, tori oun naa ti fara pa ni ikun ati apa rẹ, lasiko toun ati ọkọ rẹ n taporogan lọwọ.
O ni ko pẹ tawọn debẹ ni awọn dokita jade waa sọ fawọn pe ọkọ Maimunatu yii ti ku patapata, amọ wọn fun iyawo ni itọju pajawiri, ara rẹ si tete balẹ.
Alukoro naa fidi ẹ mulẹ pe ninu iwadii tawọn kọkọ ṣe, ọrọ ti ko to nnkan lawọn ololufẹ meji yii n fa mọ ara wọn lọwọ, o si ti fẹrẹ to wakati meji ti wọn ti n ṣe fa-a-n-fa-a ọhun tori bii aago mẹfa aṣaalẹ ni wọn ti wa lẹnu ẹ, n lọrọ naa ba di ran-n-to. Wọn ni aawọ yii lo pada di ija laarin wọn, to dogun a n ṣera ẹni leṣe, ti ọkọọyawo ṣe iyawo ẹ leṣe nikun. Ibinu eyi si niyawo naa fi wo raaraara lati gbẹsan ohun tọkọ rẹ ṣe, lo ba kuku lọọ fa ọbẹ yọ ni kiṣinni wọn, o si fibinu tẹ ẹ bọ Aliyu nigbaaya, niyẹn ba kigbe ‘oro’ o, o si ṣubu lulẹ bẹẹ.
Afurasi ọdaran yii ti jẹwọ fawọn ọlọpaa ni teṣan wọn pe loootọ loun gun ọkọ oun lọbẹ, oun o si mọ-ọn-mọ, inu lo ṣi oun bi.
Wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.