Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Chota, lorileede Peru, ti lawọn maa too bẹrẹ iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan iyaale ile kan, Abilekọ Marleni Rimarachin Colunche, ẹni ọdun mọkandinlogoji, to fibinu ati itara pe ọkọ ile oun, Ọgbẹni Ivan Cespedes ẹni ọdun mọkandinlogoji, ni ale nita, to si fọbẹ kiṣinni ge ‘kinni’ ọkọ rẹ bọ silẹ lasiko ti iyẹn n sun lọwọ.
ALAROYE gbọ pe ọdun kẹrin ree tawọn ololufẹ naa ti jọ n gbele gẹgẹ bii tọkọ-taya, ṣugbọn ti ede aiyede kekere kan ṣẹlẹ laarin wọn. Abilekọ Marleni lo fẹsun agbere kan ọkọ rẹ pe o n yan ale nita, paapaa ju lọ, nigba ti iyẹn mu ọti yo kẹri lọjọ to pẹẹ wọle. Ija nla ni Merlin gbe ko o loju, to si n pariwo buruku lọjọ naa, ṣugbọn nigba ti ko ṣetan lati gbọ alaye ti ọkọ fẹẹ ṣe lori bo ṣe pẹẹ wọle ni ọkọ ba binu lọọ sun sori bẹẹdi rẹ. Ṣugbọn ṣe ni Merlin lọọ fibinu mu ọbẹ aṣooro kan, to si fi ge ‘kinni’ ọkọ rẹ bọ silẹ. Igbe buruku ti ọkọ ọhun ke lati oju oorun lo jẹ kawọn araale ti wọn n gbe sare wa fun iranlọwọ, ti wọn si gbe ọkọ lọ sileewosan ijọba agbegbe naa ti wọn n pe ni ‘Chiclayo Hospital.’ Nigba tawọn dokita oniṣegun oyinbon to n ṣetọju rẹ ko le ṣetọju gidi fun un ni wọn ba tun gbe e digbadigba lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Lima, ti i ṣe olu ilu orileede Peru. Nibẹ lawọn dokita akọṣẹmọṣẹ ti n ṣetọju rẹ lọwọ bayii.
Ṣa o, Abilekọ Merlin ti taku pe oun kọ loun ge ‘kinni’ ọkọ oun yii, o ni ọkọ oun lo fibinu ge nnkan rẹ pẹlu ọbẹ.
Awọn ẹbi ọkọ iyawo ti Abilekọ Merlin ge ‘kinni’ rẹ ti lawọn ko ni i gba pe ki Abilekọ Merlin lọ lai jiya ẹṣẹ rẹ.
Wọn ti gba beeli Merlin bayii pe ko lọọ ṣetọju ọmọ oṣu mẹta kan to n tọ lọwọ.
Ọlọpaa olupẹjọ, Ọgbẹni Darinka Lossio, ti lawọn maa too bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn si maa foju iyaale ile ọhun bale-ẹjọ.