Iyaale ile yii rẹwọn he l’Ondo, ẹsun ole ni wọn fi kan an

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kootu Majisireeti to wa niluu Ondo, ti ni ki iya ẹni aadọta ọdun kan, Damilọla Ajayi, lọọ fẹwọn jura lẹyin ti oun funra rẹ ti gba pe oun jẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

Abilekọ yii ni wọn fẹsun kan pe o wọ ile ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni, Muhammed Abubakar, eyi to wa ni Ojule kẹsan-an, adugbo Ìgbọ́nmobà, Ṣọ̀rà, Ondo, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, nibi to ti ji owo to to bii ẹgbẹrun lọna igba Naira (#200,000).

Ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan olujẹjọ ọhun ni ọlọpaa Agbefọba, Akano Mọremi ni o ta ko abala irinwo din mẹwaa (390) ninu iwe ofin ti ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Kete ti wọn ti ka ẹsun ọhun tan ni olujẹjọ ti ko ni agbẹjọro kankan to waa gbẹnu sọ fun un ti gba pe oun jẹbi, o ni esu lo ti oun ti oun fi lọọ gbe owo olowo. Damilọla ni ẹbẹ loun n bẹ adajọ ko ṣaanu oun, ti oun ko si ni i dan iru iwa bẹẹ wo mọ laelae.

Lẹyin eyi ni agbefọba dide, to si rọ adajọ lati gbe idajọ rẹ kalẹ loju-ẹsẹ nitori ẹni to gbe panla ti jẹwọ, ọrọ ko fariwo mọ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Mosunmọla Ikujuni ni ki olujẹjọ ọhun sare lọọ fẹwọn oṣu mejidinlogun jura pẹlu iṣẹ aṣekara.

O ni anfaani kan ṣoṣo to si silẹ fun un ti yoo fi jade lẹwọn ki ọdun kan aabọ ti wọn da fun un too pe ni to ba ri owo olowo to ji gbe san fun oni nnkan pada.

Leave a Reply