Iyaale ile yii yi orukọ ọmọ mẹrin to bi fun ọkọ aarọ pada si tuntun to ṣẹṣẹ fẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn Yoruba bọ, wọn ni aya ọlẹ ni wọn n gba, ẹnikan ki i gba ọmọ ọlẹ, amọ owe yii ko jọ bii ẹni ṣiṣẹ lọdọ obinrin ọmọ Ibo kan, Chibuzor Lilian Ọbayan, pẹlu bo ṣe ko ọmọ mẹrẹẹrin to bi fun ọkọ rẹ aarọ, Ọgbẹni Ayọdeji Ọbayan, fun ọkọ tuntun to ṣẹṣẹ fẹ.

Obinrin yii ko fi mọ bẹẹ nikan, ṣe lo tun pa orukọ baba awọn ọmọ wọnyi rẹ patapata kuro ninu orukọ ti wọn n jẹ, to si fi orukọ ọmọ Ibo to ṣẹṣẹ lọọ fẹ rọpo rẹ.

Ọbayan lo mu ẹsun iyawo rẹ tẹlẹ ri ọhun lọ sile-ẹjọ, to si n bẹbẹ pe ki wọn ba oun tu ibaṣepọ ọdun mẹtalelogun to wa laarin oun ati Lilian ti i ṣe olujẹjọ ka. Bakan naa lo tun bẹbẹ pe ki kootu ba oun gba ọmọ oun mẹrẹẹrin ti obinrin yii ti ko fun ọkọ rẹ tuntun pada, nitori baba ọmọ lo l’ọmọ.

Olupẹjọ ni lati ọdun 2000, iyẹn nnkan bii ogun ọdun sẹyin loun ati Lilian ti fẹ ara awọn, ti Ọlọrun si ṣe e pẹlu bi ibaṣepọ naa ṣe so eeso ọmọ mẹrin.

O ni oun ko le sọ pato ọjọ ti oun gbadun igbeyawo ọhun latigba ti awọn ti fẹra, nitori oni ẹjọ, ọla ija, ọtunla ariwo, irọ pipa, orikunkun, ikorira oun aṣọ lawọn fi n gbe igbe-aye awọn.

O ni ọmọ Yoruba pọnbele loun, nigba ti iyawo oun jẹ ọmọ ilẹ Ibo, ọpọlọpọ iya ati ẹgbin lo ni oun ti fara da lati ọwọ awọn ti wọn jẹ ẹbi olujẹjọ nitori lati ibẹrẹ pẹpẹ loun ti mọ pe wọn ko fẹran oun rara.

Ọdun 2019 lo ni Lilian ko ẹru rẹ jade nile oun, to si lọọ fẹ ọkunrin mi-in ti wọn jọ jẹ ẹya kan naa, ti ko si fi mọ bẹẹ nikan pẹlu bo ṣe tun lọọ yi orukọ awọn ọmọ oun pada si ti ọmọ Igbo to fẹ, bẹẹ ni ko tun fun oun lanfaani lati ri awọn ọmọ naa mọ.

Ninu awijare tirẹ, Lilian ni oun pinnu ati ko ẹru oun jade niwọn igba ti olupẹjọ ti kọ lati maa ṣe awọn ojuṣe rẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ.

O ni yatọ si ọkan-o-jọkan iya to n jẹ oun nile rẹ, Ọbayan ko niṣẹ meji ju ko lu oun lalubami lọ, leyii to ṣokunfa ọpọ awọn apa to wa lara oun.

Lilian ni ọkunrin naa ki i ṣe baba to yẹ keeyan fi tọrọ baba fun awọn ọmọ oun, nitori ki i sanwo ile-iwe wọn tabi tọju wọn.

O ni olupẹjọ ko kuku sanwo kankan le oun lori, ati pe ki loun tun fẹẹ maa duro de nigba t’Ọlọrun ti gbe oun pade ọkọ gidi, ẹni to gba oun nimọran lati yi orukọ baba wọn pada si tirẹ.

Olujẹjọ ni ọrọ yii ko le rara, nitori ẹran ti ko yi ko nilo ka ṣẹṣẹ maa wa ọbẹ lati ge e, o ni awọn ọmọ naa ki i ṣe ọmọde mọ, awọn mẹrẹẹrin ni wọn ti dagba tojuu bọ lati le sọ ibi to wu wọn lati gbe.

O ni ọmọ ọdun mejilelogun ni Mayọmi to jẹ akọbi oun, nigba ti abitẹle rẹ jẹ ẹni ogun ọdun, awọn meji yooku ti wọn jẹ ọkunrin, iyẹn Ariyọ ati Aduragbemi, ni wọn wa laarin ọdun mẹrindinlogun si mejidinlogun.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Olusẹgun Rotiba rọ awọn mejeeji ki wọn gba alaafia laaye titi ti igbẹjọ yoo fi maa tẹsiwaju lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.

 

Leave a Reply