Iyawo ṣoniduuro fọkọ ẹ, niyẹn ba sa lọ, lọrọ ba di keesi

 Adewale Adeoye

Afaimọ ni iyaale ile kan to ṣe oniduuro fun ọkọ rẹ lori gbese to jẹ, ṣugbọn to sa lọ yoo fojuu re wo ọkunrin naa to ba pada de.

ALAROYE gbọ pe Ọgbẹni Augustine Ukachukwu lo parọ fun obinrin kan pe oun nilẹ toun fẹẹ ta fun un, lo ba gba miliọnu meji o le egbẹrun meji Naira (N2.2M) lọwọ rẹ, lai mọ pe ilẹ onilẹ lo gbe fun obinrin naa to pe ni tiẹ. Nigba ti akoko to ti onitọhun fẹẹ bẹrẹ si i kọle sori ilẹ naa lo ri i pe baale ile yii kọ lo ni ilẹ ọhun, ilẹ onile lo fi ṣe gbaju-ẹ foun.

Gbogbo akitiyan obinrin yii lati gba owo rẹ pada lọwọ Augustine lo ja si pabo,  eyi lo mu ko lọọ fi ẹjọ rẹ sun ni teṣan ọlọpaa.

Nigba ti awọn ọlọpaa gbọ sọrọ naa ni wọn lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ. Lẹyin naa ni wọn gba beeli baale ile yii nitori bi iyawo rẹ ti ṣe ṣoniduuro fun un niwaju igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa to da sọrọ ọhun lakooko naa. Ikilọ kan ṣoṣo ti wọn fun un ni pe ki Arabinrin Cynthia Ukachukwu maa pese ọkọ rẹ yii nigba gbogbo ti wọn ba ti nilo rẹ, eyi to kuna lati ṣe.

Ninu ọrọ ọlọpaa olupẹjọ, Haruna Magaji, nile-ẹjọ lo ti sọ pe ‘ Iwọ Arabinrin Cynthia Ukachukwu ṣe oniduuro fun ọkọ rẹ, Ọgbẹni Ukachukwu, lọjọ Keji, oṣu kẹta, ọdun 2021, niwaju igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, ni ọfiisi wọn kan to wa lagbegbe M.A. K Smith, ni Panti, niluu Yaba, nipinlẹ Eko, pe wa a maa pese ọkọ rẹ, Ọgbẹni Ukachukwu, nigbakigba ti awọn ọlọpaa ba nilo rẹ tabi pe wọn nilo rẹ nilẹ-ẹjọ.

‘‘Ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan ọkọ rẹ ni pe o ṣe gbaju-ẹ fun Arabinrin Grace, pe oun ni ilẹ kan, to si gba owo nla lọwọ rẹ ninu oṣu Kẹta, ọdun 2018 . Nigba ti onitọhun fẹẹ ṣiṣẹ lori ilẹ naa lo ri i pe oun ti bọ sọwọ gbaju-ẹ, ẹṣẹ ti ọkọ rẹ ṣe ki i ṣẹ ohun to daa rara, ijiya nla gbaa lo si wa fun ẹni to ba ṣe iru ẹ niluu Eko gẹgẹ bi ofin ilẹ wa ṣe wi.

‘‘Pẹlu bo o ṣe kọ lati pese rẹ bayii, o ti di igbẹjọ rẹ lọwọ, eyi ti ko tọna rara labẹ ofin’’.

Ṣa o, Arabinrin Cynthia Ukachukwu ti rawọ ẹbẹ si adajo ile-ẹjọ naa pe oun ko jẹbi rara. Ni bayii, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Onidaajọ O.Y Adefọpẹ sun igbẹjọ mi-in si lori ọrọ naa.

Leave a Reply