Adewale adeoye
Loni-in, ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ati iyawo rẹ, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, maa gbera kuro nile ijọba, l’Abuja, ti wọn yoo si tẹkọ leti lọ sorileede France, lati lọọ jẹ ipe pataki kan ti olori Orileede naa, Ọgbẹni Emmanuel Macron, fiwe pe wọn si. Ọjọ mẹta gbako ni Aarẹ pẹlu iyawo rẹ maa lo nibẹ.
Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ni Tinubu pẹlu iyawo rẹ maa tẹkọ leti lati papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International Airport, niluu Abuja, ti wọn aa lọ sorileede France, lati lọọ jiroro pẹlu Ọgbẹni Emmanuel Macron, ti i ṣe aarẹ orileede ọhun.
Atẹjade kan to fi sita nipa irinajo naa lo ti ṣalaye pe, ‘’Irinajo ọlọjọ mẹta kan ti Aarẹ Tinubu pẹlu iyawo rẹ n lọ fun lorileede France jẹ eyi to ṣe pataki pupọ, nitori lasiko abẹwo naa ni olori orileede mejeeji maa lanfaani lati jiroro lori ọna tawọn orileede meji naa fi maa jọ lajọṣepọ to dan mọran nipa eto iṣelu, ọrọ-aje, ohun ọgbin, eto igbani-siṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, to si maa pada ṣanfaani gidi fun orileede Naijiria lọjọ iwaju.
‘’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Aarẹ orileede France atiyawo rẹ, Abilekọ Brigitte, maa gba awọn mejeeji lalejo ni ẹka ileeṣẹ ologun orileede France, ti wọn n pe ni ‘Les-Invalides’. Nibẹ ni awọn olori orileede mejeeji naa ti kọkọ maa jiroro lori awọn ọna ibaṣepọ to yẹ ko waye laarin wọn.
‘’Ohun to daju ṣaka ni pe abẹwo naa maa ṣafaani nla fun orileede Naijiria, nitori pe oniruuru nnkan ni Aarẹ Tinubu maa sọ pẹlu Aarẹ Emmanuel Macron. Lopin ohun gbogbo, iyawo aarẹ orileede France naa maa tun ṣepade pataki pẹlu Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, lojuna ati ran awọn obinrin, awọn alaini atawọn ọmọde lọwọ.
Lẹyin naa ni Aarẹ Tinubu pẹlu iyawo rẹ maa pade sorileede Naijiria’’.