Beeyan ba gun ẹṣin ninu ọkan ninu awọn adẹrin-in-poṣonu ilẹ wa to tun jẹ oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Kwara, Abdugafar Ahamad, tọhun ko ni i kọsẹ. Eyi ko sẹyin bi Ọlọrun ṣe fi ọmokunrin lanti lanti ta oṣere naa lọrẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii.
Iyanu to wa nibẹ ni pe orileede Saudi lo bi omọ naa si, iyẹn lasiko ti oun ati iyawo rẹ lọ fun Hajj ọdun 2023 yii.
Tidunnu tidunnu ni ọmọkunrin to ti figba kan jẹ ọkan lara awọn ọmọ ogun oju omi ilẹ wa ko too fẹyinti yii fi gbe e sori Instagraamu rẹ pe oun naa ti di baba ikoko.
Oṣere naa gbe fọto oun ati iyawo rẹ bi wọn ṣe wa ni Mecca, ati ti ọmọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bi ọhun naa sori ikanni rẹ, o si kọ ọrọ sabẹ fọto naa pe, ‘ọkunrin ko ti i pe gẹgẹ bii ọkunrin, afi ti oun naa ba bi ọmọ saye. Emi naa ti ni ọmọkunrin bayii o, Alaaji si ni. Mo dupẹ lowọ rẹ, ololufẹ mi.’’
Bi Cute Abiọla ṣe kọ ọrọ naa niyi, ti iyawo rẹ naa si kọ ọ sori ikanni tiẹ pe, ‘ọmọkunrin ni, Mecca la si bi i si’
Latigba ti oṣere ọmọ bibi ilu Ilorin naa ti gbe iroyin ayọ yii sori ikanni rẹ ni awọn ololufẹ rẹ atawọn elẹgbẹ rẹ gbogbo ti n ki i ku oriire, ti wọn si n gbadura fun iya at’ọmọ naa.
Lara awọn ti wọn ti ba Abiọla dawọ idunnu ni Fẹmi Adebayọ, Kie-kie, Mo-Bimpe, Jiganbabaọja, Funmi Awẹlẹwa ati bẹẹ bẹẹ lọ.