Iyawo fi háámà fọ adajọ lori, o lo n yan ọkọ oun lale

  Obinrin adajọ kan torukọ ẹ n jẹ Tamara Chibindi, ko ti i bọ ninu wahala to ko si latọwọ obinrin ẹgbẹ ẹ to la haama mọ ọn lori lọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun 2021 yii. Niṣe ni ori naa bẹjẹ, ti wọn sare gbe e lọ sọsibitu fun itọju pajawiri, ko si ti i yee we egbo rẹ titi disinyi.

Orilẹ-ede Zimbabwe niṣẹlẹ yii ti waye. Thelmor Mudhefi lorukọ iyawo to la haama mọ Tamara lori, ohun to sọ ni pe o n yan ọkọ oun ti iṣẹ jọ pa wọn pọ lale. Lọọya lọkọ obinrin yii, orukọ ọkunrin naa ni Chris Ndlovu.

Iyawo Chris lọọ ba Adajọ Tamara nile ẹ ni o, o loun ti gbọ, oun si ti mọ pe alajọpin oun nibi ibasun ni, ki i ṣe iṣẹ nikan lo da oun ati ọkọ oun pọ, iyẹn loun ṣe waa da sẹria naa fun un nile rẹ.

Ẹka iroyin Zimlive to fi iṣẹlẹ yii sita ṣalaye pe ki i ṣe ori nikan ni iyawo to n binu naa ti la haama mọ adajọ, wọn lo tun fi nnkan ge e lọwọ, to jẹ niṣe ni wọn sare ba a ran awọn oju ọgbẹ naa nileewosan.

Loootọ ni wọn fọwọ ofin mu iyawo lọọya to la haama mọ adajọ lori yii, ti adajọ si ti pe ẹjọ ta a ko ni kootu, sibẹ, obinrin naa ko ti i gbadun titi dasiko yii, o ṣi n gba itọju lọsibitu ni, latari kinni to le gba ẹmi lẹnu eeyan ti Thelmor la mọ ọn lori naa.

 

Leave a Reply