Stephen Ajagbe, Ilorin
Iyawo gomina Kwara, Olufọlakẹ Abdulrazaq, ti fi Risikatu Abdulazeez, obinrin toju oun atawọn ọmọ rẹ yatọ, sẹnu ikọṣẹ ṣiṣe oge (make-up) fawọn obinrin ati gele wiwe, labẹ ajọ Ajikẹ People’s Support Centre niluu Ilọrin. Olufọlakẹ tun ṣeleri lati ran ọkọ rẹ, Abdulwasiu, lọwọ lati jẹ ki iṣẹ rẹ to n ṣe tun gberu si i.
Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Adeniyi Adeyinka, lo fidi rẹ mulẹ fun akọroyin wa lori foonu laaarọ oni yii pe iyawo gomina ni ki Risikatu maa kọ iṣẹ oge ṣiṣe naa na, ko ma ba a maa jokoo sile lasan.
O ni iwadii ti n lọ nileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ilera nipinlẹ Kwara lati mọ boya obinrin naa kọṣẹmọṣẹ nipa oogun tita to loun kọ, paapaa julọ lati yẹ iwe-aṣẹ to loun ni lọwọ wo, boya o jẹ ojulowo.
O ṣalaye siwaju pe lẹyin ti wọn ba ri i pe o wẹ yan kainkain nipa ogun tita, wọn yoo jẹ ko pada sẹnu iṣẹ naa.
Ajikẹ People’s Support Center jẹ ibudo ti wọn ti n ran awọn to ku diẹ ka a to lọwọ, nipa kíkọ wọn ni oriṣiiriṣii iṣẹ-ọwọ, ki wọn le da duro laaye ara wọn.
Abdulwasiu to jẹ ọkọ rẹ naa fidi ẹ mulẹ fun akọroyin wa. O ni aya gomina pe awọn mejeeji si ipade alaafia nibi tawọn ti jọ wọ ankoo, o si rọ wọn lati gba alaafia laaye laarin ara wọn.
Abdulwasiu ni yatọ si eyi, o tun ṣeleri lati ba Risikatu gba iwe aṣẹ ati lati ran an lọwọ to ba si nifẹẹ si iṣẹ ogun tita to fi aarọ ọjọ rẹ kọ. O ni inu oun dun si igbesẹ tiyawo gomina gbe naa nitori pe yoo din bukaata ku lori oun nikan, yoo si fun iyawo ouon lanfaani lati maa ran oun lọwọ.
Ọkunrin ọhun ni bi oun ba le ni ṣọọbu toun nibi ti oun yoo ti maa fẹ taya, ti oun yoo si tun maa ta taya, iun oun yoo dun, nitori o maa din iya to n jẹ awọn ku.
Ẹgbọn Wasiu, Aafaa Jamiu Imaamu Ọlọmọyọyọ, fidi ọrọ mulẹ pe loootọ ni ija ti pari. O ni mọlẹbi awọn dupẹ lọwọ gbogbo awọn to da si i, pataki julọ iyawo gomina Kwara, fun iranlọwọ to ṣe fun Wasiu ati iyawo rẹ.