Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọpọ igbeyawo lo n daru nitori pe awọn ọkọ n fiya jẹ awọn iyawo wọn, ṣugbọn ni ti idile Ronald Kaputo, ni Zamfara, ọkọ gan-an lo kegbajare sita, o ni iyawo oun ti fẹẹ gbẹmi oun. Lo ba gbe e lọ si ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa nijọba ibilẹ Kabushi, niluu Zamfara. Nibẹ lo ti rọ adajọ kootu naa lati tu igbeyawo oun pẹlu iyawo ẹ, Maggie Chiluba, ka.
O ni yatọ si pe iyawo oun maa n fi ẹsun agbere kan oun, aimọye igba lobinrin naa maa n fi bileedi tọ awọtẹlẹ oun lati yẹ nnkan ọmọkunrin oun wo boya oun ti lọọ yan ale nita, ti apa oun ko si ka obinrin ti oun fowo ara oun fẹ sile yii mọ rara.
“Nigba miiran to ba ni ki n ba oun laṣepọ ti mo ba sọ pe o ti rẹ mi, yoo maa binu ni. Yoo maa yẹ nnkan ọmọkunrin mi wo ni, ti yoo si maa fẹsun kan mi pe mo ti lọọ ṣagbere pẹlu awọn obinrin miiran nita.
Ti mo ba wọ awọtẹlẹ ki n too sun, yoo fi bileedi tọ ọ. Mi o ri alaafia kankan ninu igbeyawo yii. Ohun lo gbe mi debi, ki ẹ le saanu mi, ki ẹ tu wa ka”.
Yatọ si eleyii, baale ile yii ni, “iyawo mi ki i bọwọ fun mi, koda, o lagbara debii pe o ti da itọ le mi lori ri lasiko ti mo n sun lọwọ. Bakan naa ni yoo maa rojọ ile wa kiri fawọn araadugbo.
Iyawo mi ko nifẹẹ awọn mọlẹbi mi rara, nigbakugba ti wọn ba waa ki wa, yoo maa fẹsun kan wọn ni pe wọn wa lati da ile wa ru’’.
Ninu ọrọ olujẹjọ, Maggie, o ni loootọ ni ko si ọmọ laarin igbeyawo ọdun mẹrin yii, ṣugbọn awọn n gbe igbe alaafia lati ọdun mẹrin ṣẹyin, oṣu Keji, ọdun yii, ni Ronald bẹrẹ si i pẹẹ wọle.
“Alẹ ọjọ kan, mo n yọ tẹle e lẹyin to fi wọ inu ile kan lọ. Mo kan ilẹkun ferese ile naa, o jade sita, o si bẹrẹ si i lu mi nisoju ọrẹbinrin rẹ”.
Maggie ni latigba naa loun ko ti ni ifọkanbalẹ ninu igbeyawo oun mọ. O ni awọn wa sile-ẹjọ ki wọn le pẹtu sawọn lọkan ni, nitori pe oun ṣi ni igbagbọ ninu igbeyawo naa.
Awọn meji ti wọn gbẹjọ naa, John Kabwe ati Emeldah Masuwa, pari ija laarin tọkọ-taya yii, wọn si kọ wọn bi wọn yoo ṣe maa gbe pẹlu alaafia.