Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kayeefi patapata ni iṣẹlẹ iku gbajugbaja babalawo kan to filu Ikẹrẹ-Ekiti tii ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ikẹrẹ nipinlẹ Ekiti ṣebugbe, Alagba Fadayọmi Kẹhinde, ẹni tọpọ awọn eeyan ilu ọhun mọ si Ejiogbe, ṣi n jẹ loju awọn to gbọ iroyin naa titi di ba a ṣe n sọrọ yii.
Kii kuku ṣe oni lawọn eeyan ti n ku, nitori ko si ojulowo ọmọ Yoruba ti ko nigbagbọ ninu owe awọn agba kan to ni ‘ko sẹni ti ko ni i ku, bẹẹ ni ko sẹni ti oko baba rẹ ko ni i d’igbòrò, dandan niku, gbogbo wa la jẹ gbese rẹ, ṣugbọn ọna ti babalawo ti wọn lo jẹ ọmọ bibi ilu Ondo ọhun gba jẹ ipe Olodumare, to si ṣe bẹẹ pada sajule ọrun lo n ya ọpọ awọn eeyan lẹnu.
Ariyanjiyan pupọ awọn to n ka nipa iṣẹlẹ kayeefi ọhun ni pe to ba jẹ loootọ ni Ejiogbe jẹ ojulowo babalawo to mọ Ifa rẹ dajudaju, ko yẹ ko lu magun lara obinrin, to ba si ṣeesi lu u paapaa, ko yẹ ko jẹ ohun ni yoo ran an sọrun ọsan gangan.
Idi ree ti akọroyin ALAROYE ṣe ṣabẹwo si ilu Ikẹrẹ-Ekiti, nibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ lati mọ bi ọrọ naa ṣe jẹ gan-an.
ALAROYE gbiyanju lati ṣawari Ẹfanjẹliisi Rita Ajagun Igbala, iyẹn iyawo pasitọ ati oludasilẹ ijọ ti wọn ni Ejiogbe ku sori rẹ ninu ileetura kan ta a forukọ bo laṣiiri, eyi to wa loju ọna marosẹ Ikẹrẹ si Akurẹ.
Bakan naa la tun gbiyanju lati wa ọmọ ati ẹnikan to jẹ ọrẹ timọtimọ oloogbe ọhun ni awari lati le fidi ohun to ṣẹlẹ gan-an mulẹ.
Ninu alaye soki ti obinrin naa ṣe lasiko ti wọn n fi ọrọ wa a lẹnu wo ni tesan ti wọn mu un lọ lo ti sọ pe loootọ loun ati Ejiogbe n yan ara awọn lale, ati pe ki i ṣe igba akọkọ niyẹn tawọn n ṣe ‘kinni’ fun ara awọn.
Rita ni, ‘‘Awọn ni wọn pe mi lanaa pe ki n waa ba awọn ni (otẹẹli ta a forukọ bo laṣiiri). Mo si lọọ ba wọn nibẹ. Mo sọ fun wọn gan-an pe mo bisi, pe a n ṣe nnkan, wọn ṣaa ni ki n wa, atẹranṣe ti wọn fi ṣọwọ si mi paapaa wa lori foonu mi. Emi ati Ejiogbe atawọn ọrẹ rẹ meji mi-in la jọ kọwọọrin lọ si otẹẹli ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii. Lẹyin ta a ṣe faaji tan ni a jọ wọ yara lati gbadun ara wa.
‘‘Ki i ṣe loju-ẹsẹ ta a wọnu yara otẹẹli yẹn la bẹrẹ si i ba ara wa sun. Ejiogbe kan sun le mi lori lasan ni, a si n ba ara wa ṣere ko too di pe a maa ba ara wa lo pọ ni wahala ti bẹrẹ. Bi wọn ṣe gun ori mi ni wọn ṣubu si ori bẹẹdi, wọn bẹrẹ si i gbọn pipi, wọn n gbọn gidigidi, bẹẹ ni wọn n ta wọn-in wọn-in. mo waa n pe wọn pe daadi, ki lo ṣe yin, mo waa lọọ pe Ọga Bayọ to gbe wọn wa, mo lọọ pe e nita. Eyi ti Ọga Bayọ naa iba fi wọle ko wo nnkan to ṣe wọn, ko wọle, o waa lọọ pe awọn Abbey atawọn yooku wa, la waa sare gbe wọn lọ si ọsibitu, nibẹ ni wọn ti sọ pe wọn ti ku. Ki i ṣe pe ori mi ni wọn ku si tabi pe lasiko ti a n ba ara wa lo pọ lo ku bi awọn kan ṣe n sọ’’.
Babalawo mi-in to jẹ ọrẹ timọtimọ fun Oloogbe Fadayọmi, Alagba Ifadamitan Oni, naa b’ALAROYE sọrọ lori ohun to mọ nipa ọrẹ rẹ, eyi lohun to sọ fun akọroyin wa nipa Ejiogbe.
‘‘Mo mọ Oloogbe Fadayọmi daadaa, eeyan rere ni, ogbontarigi ni ninu iṣẹ awo, ẹni ti mo le fọwọ rẹ sọya pe o mọ Ifa ati ọpẹlẹ ni amọdaju ni.
Ọpọlọpọ ọdun lemi pẹlu rẹ fi jọ gbe, ta a si jọ n ṣiṣẹ awo ni Ikẹrẹ-Ekiti, ko too di pe mo pada si ipinlẹ Ọṣun, nibi ti mo ti n ba yin-in sọrọ lọwọlọwọ. Nibi ti ọrẹ wa mulẹ de, ọwọ mi bayii lo bi gbogbo awọn ọmọ rẹ si.
‘‘Ṣẹ ẹ ri i, ti inu eeyan ba ti mọ ni amọju nigba miiran, wahala nla lo maa n da si ni lọrun. Gbara ti iṣẹlẹ ọhun sẹlẹ ni wọn pe mi, mo si pe ọmọ rẹ pe bawo lo ṣe jẹ? Alaye ti wọn ṣe fun mi ko yatọ rara si ohun ti ọrẹbinrin rẹ ti wọn jọ wa ninu yara otẹẹli ṣe.
‘‘Wọn ni wọn o ti i maa ba ara wọn sun, ere lasan ni awọn ṣi n ṣe lọwọ to fi bẹrẹ si i pọkaka iku, ki i ṣe pe o takiti gẹgẹ bii ahesọ ti wọn n sọ kiri. Nigba ti mo beere ohun to le ṣẹlẹ lọwọ awọn babalawo miiran to jẹ ẹgbẹ wa, awọn naa jẹ ko ye mi pe magun ni loootọ.
‘‘Ninu ero temi, mi o nigbagbọ rara ninu ọrọ tawọn awo ẹgbẹ wa n sọ pe magun lo pa Ejiogbe, awọn babalawo to n sọ bẹẹ gan-an le jẹ ọta rẹ loju aye, ṣẹ ẹ mọ pe inu ọpọlọpọ ni ki i dun nigba ti wọn ba ri babalawo to n ṣe daadaa, to n kọle mọle, to si n ralẹ mọ ilẹ ninu iṣẹ awo ṣiṣe.
‘‘Wọn le ni ṣe lo dọgbọn sọrọ ara rẹ tabi pe o tẹ ọrọ rẹ nidii, gbogbo ọgbọn ati ọna ti wọn yoo fi maa ṣaata tabi ki wọn fa a lulẹ ni wọn aa maa wa kiri.
‘‘Ọkan ninu awọn ọmọ rẹ to ba mi sọrọ ni, nigba to ku tan ti awọn yẹ ẹnu rẹ wo, o ni ṣe lọna ọfun rẹ bo tooroto lọ sisalẹ inu rẹ lọhun-un, ẹ sọ fun mi, ṣe eniyan le ku iku magun ki ọna ọfun rẹ waa bo?
‘‘Alaye ti ọmọ yẹn ṣe fun mi siwaju ni pe, wọn gba awọn nimọran lati gbe baba awọn lọ sibi ti wọn ti n ṣe ayẹwo lati mọ iku to pa a, ṣugbọn aisi owo lọwọ awọn ni ko jẹ kawọn le ṣe bẹẹ, ti awọn si gba kamu lori ọrọ naa. Ọmọ yii fi da mi loju pe majele ni wọn fun baba oun jẹ, magun kankan ko pa a.
‘‘Ẹyin naa le ṣe akawe ọrọ ọmọ oloogbe pẹlu ọrọ ti obinrin ti wọn jọ gbe ara wọn lọ si otẹẹli sọ, ẹ maa ri i pe oju kan naa lo bọ si, awọn agba bọ, wọn ni o jọ gàté kò jò gate, o fẹsẹ mejeeji tiro gátegàte.
‘‘Ẹdẹ ni wọn fi iṣẹlẹ yii ṣe fun Ejiogbe, emi o gbagbọ pe magun lo pa a o’’
. Ọmọ-awo mi-in to tun ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Alagba Ọjẹlabi Ọlatubọsun, ni ọrọ magun lilu ki i ṣe nnkan babara nilẹ Yoruba, o ni ẹnikẹni lo le lu u, yala o jẹ babalawo, afaa tabi pasitọ.
O ni ṣebi awọn iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe pasitọ to jẹ ọkọ obinrin ọhun funra rẹ ti fi igba kan lu magun lori rẹ ri. Alagba Ọjẹlabi ni ṣe ọkunrin to pe ara rẹ ni ojuṣẹ Ọlọrun naa le bura pe omi adura lo ko oun yọ tabi awọn nnkan ibilẹ tabi ajẹsara to ni ti kinni ọhun ko fi ṣeku pa a.
O ni awọn ẹgbẹ awo lorilẹ-ede Naijiria ti pade lati jiroro lori iṣẹlẹ ọhun, ati pe ere lo ba ẹdun Ejiogbe nilẹ to di ọlẹ, ibi ti iṣẹlẹ naa si ka ogboju babalawo naa mọ, ko sohun ti eeyan le ṣe si i, nitori ko sẹni ti ko le ṣẹlẹ si.
Awọn ọmọ oloogbe yii sọ fun akọroyin wa pe ẹnikan to wa nitosi lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye sọ foun pe baba oun n pọ nnkan dudu lẹnu nigba to ku tan.
Ọmọbinrin to kọ lati darukọ ara rẹ naa sọ fun wa pe, gbogbo eeyan lo mọ pe ẹni ti wọn ba fun ni majele jẹ nikan lo le maa pọ nnkan jade lẹnu lẹyin to ba ku.
ALAROYE de ibi ti ṣọọṣi ọhun wa nibi kan ti wọn n pe ni Ilẹ Mimọ, eyi to wa lẹyin ileepo kan ti wọn n pe ni Sadesh, lagbegbe Oke-Ọṣun, lẹbaa oju ọna marosẹ Ikẹrẹ si Akurẹ.
Ori apata kekere kan ni wọn kọ sọọsi ọhun si pẹlu pako, ti ile pasitọ ati iyawo rẹ naa si wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ijọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ti gbogbo awọn Onigbagbọ maa n ṣe isin ọjọ isinmi lakọroyin wa ṣe abẹwo sibẹ, a ko ba ẹnikẹni ninu sọọsi ọhun tabi ninu ile, paroparo ni gbogbo ibẹ da, ti wọn si tilẹkun ile-ijọsin ati ile naa pa.
Araadugbo kan ta a fọrọ wa lẹnu wo lo jẹ ko ye wa pe ko daju pe wọn ṣe isin kankan nile ijọsin ọhun lọjọ naa. O ni oun mọ pasitọ to jẹ oludasilẹ ṣọọṣi naa ati iyawo rẹ daadaa. O ni ọkọ obinrin ti wọn n pe ni Ledi Ẹfangẹliisi ọhun ni awọn ijọ mi-in kaakiri niluu Ikẹrẹ-Ekiti, yatọ si ibi ta a ṣe abẹwo si.
O ni iyawo rẹ, Rita, ti Ejiogbe ku mọ lori lo fi si ṣọọṣi ta a ṣe abẹwo si lati maa mojuto o. Obinrin to ba ale lọ sotẹẹli naa ni Ledi Ẹfangẹliisi ori ijọ naa latigba ti wọn ti da a silẹ, ati pe o ṣee ko jẹ ohun lo ṣokunfa bi wọn ṣe waa ba awọn nnkan jẹ nibẹ.
O ni itiju ni ko jẹ ki obinrin ọhun le wa sile tabi inu ijọ wọn mọ nitori oun gbọ pe ko si ni teṣan mọ, awọn ọlọpaa ti da a silẹ.
Abilekọ ọhun ni ohun ti oun ṣakiyesi ni pe awọn eeyan naa n yọ wa lalaalẹ lati ko ẹru wọn kuro ninu ile wọn ti awọn ọmọlẹyin Ejiogbe ṣe akọlu si nigba ti wọn gbọ iroyin iku rẹ.
Ẹlomin-in to tun ba kọroyin wa sọrọ, ṣugbọn to kọ lati darukọ ara rẹ ṣalaye pe ija ti wa laarin pasitọ yii ati ọkunrin babalawo naa lori bo ṣe n yan iyawo rẹ lale. Wọn ni pasitọ yii ti lu magun lara iyawo rẹ yii ri, ti ọrọ naa si di wahala nla, to jẹ pe awọn mọlẹbi pasitọ yii lo ba wọn da sọrọ naa.
ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn babalawo to gbajumọ daadaa niluu Ikẹrẹ-Ekiti, to si ri jajẹ nidii iṣẹ to yan laayo yii ni ọkunrin naa. O jọ pe owo to wa lọwọ rẹ yii lo fi n fa oju obinrin naa mọra ti wọn fi n yan ara wọn lale.
Ki i ṣe pe ile Ejiogbe ati ti ọkọ ale rẹ wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ gẹgẹ bii iroyin ti wọn n gbe kiri, loootọ ni ile awọn mejeeji ko jinna sira, adugbo kan pere lo wa laarin ile Ejiogbe Fadayọmi pẹlu ibi ti ile ati ṣọọṣi wọn wa. Bi ẹni kan ba wa ni ile tirẹ, ketekete ni yoo maa wo ile ẹni keji lọọọkan.
Loootọ ni wọn ba sọọsi ati ile obinrin naa jẹ, wọn ja pako ti wọn kan mọ ara ṣọọṣi yii yipo, wọn ya aṣọ oju fereṣe, bẹẹ ni wọn ko awọn aga ati ẹrọ amohun-bu-gbamu (speaker) kan jade ti wọn si ba wọn jẹ.
Lẹyin eyi ni wọn waa fabọ si ori ile wọn ti wọn n kọ lọwọ, eyi ti wọn ko ti i pari tan, niṣe ni wọn fi ibinu ja igi ati tapoli ti wọn kan mọ oju fereṣe wọn.
Gbogbo akitiyan wa lati ri manija ileetura ti Ejiogbe ku si ba sọrọ lo ja si pabo pẹlu bi wọn ṣe ni ọkunrin naa ko si nitosi lasiko ta a ṣabẹwo si otẹẹli naa.
Nigba ti akọroyin wa de ile Oloogbe Fadayọmi, eyi to wa laduugbo Folufash, a ri i pe wọn ti sin oku ọkunrin babalawo naa siwaju ita ile rẹ, bẹẹ ni a ko ri ẹnikẹni ta a le fọrọ wa lẹnu wo lasiko ta a de bẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to mkọja ni ariwo deede gba ilu kan pe babalawo u sori iyawo pasitọ to jẹ ale rẹ.