Johnson fẹẹ farugbo ara ṣẹwọn ni Kwara, o lu ẹni to fẹẹ gbale lọwọ ẹ ni jibiti

 Bi wọn ba n ṣadura pe keeyan ma ri idaamu lọjọ alẹ rẹ, boya ni baba agbalagba yii, Johnson Oluwọle, ẹni ọdun mejidinlaaadọrin yii le ṣamin adura naa mọ o, tori ọkunrin naa ti ko ara ẹ sinu iyọnu ati aapọn gidi bayii latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o lu obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Amusan Iyanuoluwa, ni jibiti owo nla, awọn agbofinro si ti mu un.

Afurasi Johnson Oluwọle, lo ti n ṣẹju peu lakolo ọlọpaa nipinlẹ Kwara bayii fẹsun pe o lu jibiti  ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira (80,000), pẹlu adeun pe oun yoo fi ile rẹnti fun un.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi, Iyanuoluwa, lo mu ẹsun lọ si teṣan wọn to wa ni ilu  Ògèlé, nipinlẹ Kwara, pe baba kan torukọ rẹ n jẹ Johnson Oluwọle Aguda, to n gbe ni No 9, Orísúnnbáre, lagbegbe Múbọ̀, niluu Ilọrin, gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira lọwọ oun lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, pẹlu adehun pe yoo gbe ile apatimẹnti oni yara kan (a room self contain apartment)  toun fẹẹ maa yaa gbe fun oun, ṣugbọn lọjọ keji toun ko ẹru lọ sile naa loun ba ayalegbe mi-in ninu ile. Gbogbo igbiyanju oun lati gba owo oun pada lọwọ baba naa lo ja si pabo.

Wọn ni Johnson tọwọ bọ’we adehun lagọọ ọlọpaa lọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, pe oun yoo da owo naa pada lọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ṣugbọn o kuna lati da owo naa pada, ni wọn ba lọọ fi ọwọ ofin mu un, ti wọn si ti taari ẹ lọ siwaju ile-ẹjọ Majisireeti bayii, nibi ti yoo ti lọọ kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Leave a Reply