Joy gun ọmọ ẹ to ṣẹṣẹ bi pa, o niyaa oun lo ni koun ṣe bẹẹ

Jọkẹ Amọri

Niṣe ni awọn abiyamọ, atawọn eeyan adugbo kan to wa ni Olocha-Adogba, ni Agwu, nijọba ibilẹ Awgu, nipinlẹ Enugu, tu jade, ti wọn si n fi ẹhonu han ta ko bi ọdaju ọmọbinrin kan ti ko ju ẹni ọdun mejidinlogun lọ, Ada Jọy Okonkwo, ṣe pa ọmọ to ṣẹṣẹ bi, to ni iya oun lo ni ki oun gun ọmọ naa pa. Wọn ni iwa ọdaju gbaa lọmọbinrin yii hu.

Ọmọbinrin eni ọdun mejidinlogun naa lo loyun, o si fi oyun naa bi ọmọkunrin kan. Ko sẹni to waa mọ ohun to ṣẹlẹ ti iya to bi ọmọbinrin yii, Christiana Okonkwo, ẹni ọgọta ọdun, fi gba a nimọran pe ko lọọ pa ọmo naa sọnu.

Awọn kan n sọ pe nitori pe ọmọ to ṣẹṣẹ bi yii ko ni baba ni, nitori oyun oge ni ọmọbinrin naa ni lo fa a to fi ni ko ṣe bẹẹ.

Lọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni wọn ni Joy bimọ, ṣugbọn iya rẹ gba a niyanju pe ko pa ẹjẹ ọrun ọhun yii lẹyin iṣẹju diẹ to bi i. Joy naa ko beṣu-bẹgba, niṣe ni wọn lo mu ọbẹ ni kiṣinni, lo ba fi gun ọmọ naa pa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn pada sare gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu lati du ẹmi rẹ, gẹgẹ bi Aluukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, Daniel Ndukwe, ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita, awọn dokita sọ pe ọmọ naa ti ku. O ni awọn kan ni wọn fi iroyin iṣelẹ naa to awọn leti pe ọmọbinrin kan yọ ọbẹ ninu ile idana, o si fi gun ọmọ tuntun to ṣẹṣẹ bi pa. O ni wọn sare gbe ọmọ naa lọ sileewosan lati du ẹmi rẹ, ṣugbọn o ti ku. Oju-ẹsẹ ni wọn si ti gbe e si ile igbokuu-pamọ si fun ayẹwo.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Ahmed Ammani, ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to n wadii iwa ọdaran wadii iṣẹlẹ naa daadaa, ki wọn si foju iya atọmọ yii bale-ẹjọ leyin iwadii.

 

Leave a Reply