Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ redioniiki kan, Julius Badejọ, lori ẹsun lilu ọrẹkunrin iyawo rẹ, Isaac Bolodeoku pa, niluu Ondo.
Ni ibamu pẹlu ohun ta a gbọ, o ti n lọ si bii ogun ọdun ti Julius ati iyawo rẹ, Abilekọ Abiye Ọlayẹle, ti n gbe pọ gẹgẹ bii ọkọ ati aya.
Ọmọ marun-un lo wa laarin awọn mejeeji, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin ọmọ bibi ilu Ondo ọhun ko ti i fẹ iyawo rẹ nisu lọka.
Lati bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin ni wọn ni ija buruku ti n waye laarin Julius ati iyawo rẹ, airi ọrọ ija yii yanju lo ṣokunfa bi awọn ẹbi obinrin ti wọn n pe ni Iya Marvelous naa ṣe binu lọọ ko ẹru rẹ kuro nile baba awọn ọmọ rẹ.
Adugbo kan ti wọn n pe ni Ẹbunoluwa, Ayeyẹmi, lo lọọ da gba ile tirẹ sì, to si ko gbogbo awọn ọmọ to bi tira, to n da tọju wọn.
Ibẹrẹ ọdun to kọja ni iya ọlọmọ marun-un ọhun pade Isaac labule Laoṣo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, nibi to ti n sisẹ lebira lẹyin to ko kuro nile ọkọ.
Ọjọ aisun ọdun to kọja lawọn ololufẹ tuntun naa pada siluu Ondo, ile ti Abilekọ Abiye n gbe ni Ẹbunoluwa lawọn mejeeji si de si fun ayẹyẹ ọdun.
Lojiji ni wọn deedee ri Julius to waa ka wọn mọle lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, to si bẹrẹ ijakadi nla pẹlu Isaac to jẹ ọrẹkunrin iyawo rẹ.
Wọn ni bo ṣe kọkọ wọnu yara to ba a nibi to sun si lori bẹẹdi lo rọ omi koroba nla kan le e lori, leyii to mu ko tete taji loju oorun to wa.
Níbi to ti n gbiyanju ati rọna sa jade ninu yara lo tun ti gba a mu, to si la pako nla kan tọwọ rẹ ba lasiko naa mọ ọn lori.
Awọn to wa nitosi gbiyanju lati du ẹmi rẹ loootọ pẹlu bi wọn ṣe sare gbe e lọ si awọn ileewosan kan, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.
Ninu ọrọ ti Abilekọ Abiye b’ALAROYE sọ nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, igba ti ọkọ oun fẹẹ fi iya gbẹmi oun loun ko kuro nile rẹ tọmọtọmọ lati lọọ maa ṣiṣẹ lebira labule Laoṣo.
Lati bii ọdun mẹta sẹyin ti wọn ti pinya lo ni oun ti pinnu pe ko si ohun to tun le pa oun pẹlu rẹ pọ mọ latari iya to ti fi jẹ oun.
O ni funra oun loun da gba ile ti oun n gbe lati igba naa, ati pe laipẹ yii ni oloogbe ṣẹṣẹ ba oun da sọrọ owo ile sisan.
Alagba Adeṣemoye Ọladuti to jẹ ẹgbọn abilekọ naa kin ọrọ aburo rẹ lẹyin ninu alaye diẹ to ṣe fun wa. O ni funra oun loun lọọ binu ko ẹru rẹ kuro nile Julius nigba to fẹẹ fi lilu rán án lọrun ọsan gangan. Bẹẹ lo si fọ igo mọ obinrin kan to jẹ aburo iyawo rẹ lori lọdun to kọja.
O juwe ana rẹ yii gẹgẹ bii onijagidijagan eeyan, gbogbo awọn ẹbi rẹ lo ni wọn ti kẹyin si i latari iwa ki i gbọ, ki i gba, to n hu.