Gbenga Amos, Ogun
Ọba alaye kan, Ọba Nureni Oduwaye, ti n kawọ pọnyin rojọ ni kootu Majisreeti to wa niluu Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o ṣe ọkunrin oniṣowo kan, Wasiu Oduwọle, leṣe. Wọn lo lu ọkunrin naa fọ loju nigba tinu bi i tori iyẹn ba ọkan ninu awọn olori rẹ jo lagbo ariya.
Ba a ṣe gbọ, ayẹyẹ ọjọọbi gbajumọ obinrin tawọn eeyan mọ si Iyalaje lagbegbe ọhun lo waye ni otẹẹli Moore Blessing, niluu Ikẹnnẹ, loṣu kẹsan-an to lọ yii, Oduwaye ati olori rẹ si wa lara awọn alejo pataki ọjọ naa.
Wasiu yii ni wọn gbe iṣẹ agbaṣe fun lati pese gbogbo jijẹ mimu nibi ariya ọhun, lẹyin ariya ni olori lọọ fẹsẹ rajo loju agbo, awọn eeyan si ba a jo loriṣiiriṣii, wọn ni Wasiu naa n jo loju agbo lasiko naa.
Gẹgẹ bi alaye ti alayẹyẹ ọjọ naa ṣe fun iweeroyin Punch, o ni ojiji ni Kabiyesi yii fibinu dide, to si kọja sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, awọn si lọọ ba a, Wasiu naa lọ pẹlu, tori wọn kọkọ lero pe boya ipese ọbẹ alata pẹpẹsuupu ọjọ naa ko tẹ ọba yii lọrun lo tori ẹ binu ni, ni wọn ba lọ bẹ ẹ.
Wọn niṣe ni Wasiu yii dọbalẹ gbalaja lati bẹ kabiyesi, ṣugbọn ọba naa ko gbẹbẹ, kaka bẹẹ, niṣe lo fun Wasiu nipaa loju, o si fi bata rẹ ṣe e leṣe. Bẹẹ ni wọn lọkunrin yii kerora oju oun, awọn mọlẹbi rẹ gbe e lọ sileewosan, atigba naa ni wọn ti fi bandeeji de oju rẹ. Lẹyin eyi lọrọ di tọlọpaa, awọn ọlọpaa si ṣewadii. Abọ iwadii wọn lo mu ki wọn pinnu lati wọ ọba alaye naa lọ sile-ẹjọ.
Ni kootu, ẹsun meji ti wọn fi kan Ọba Oduwaye ni pe o ṣe ọmọlakeji rẹ leṣe gidi, o si tun da alaafia ilu ru.
Iwe ẹsun naa ka lapa kan pe: “A fẹsun kan ọ, pe iwọ Ọba Nureni Oduwaye, huwa to tapa sofin, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, nipa tita Ọgbẹni Wasiu Oduwọle nipaa loju, ti o si fi bata rẹ ṣe ẹyinju apa osi rẹ leṣe, eyi to lodi sofin, ti ijiya to gbopọn wa fun labẹ ofin ojilelọọọdunrun din marun-un iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2006 ti ipinlẹ Ogun n lo.
Bo tilẹ jẹ pe ọba naa loun ko jẹbi, ile-ẹjọ ti sun igbẹjọ rẹ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.