Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Saheed Abdullahi, ti dero ile-ẹjọ o. Kamẹra ileefowopamọ (First bank), ẹka tilu Ilọrin, lo n lọọ fọwọ yi sodi ti wọn fi mu un, lo ba ni iṣẹ aye ni.
L’Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii, ni ọlọdẹ to n ṣọ ileefowopamọ naa torukọ rẹ n jẹ Jimọh pe awọn ọlọpaa, o ni ki wọn waa mu Saheed fẹsun pe o wọ inu banki lai ni idi Pataki, to si n huwa ko tọ nipa fifọwọ yi ẹrọ aṣofofo to wa ni banki naa.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu yii, ni wọn taari re lọ si kootu. Jimoh ṣalaye fun adajọ pe nibi toun jokoo si loun ti n wo Abdullahi lọọọkan to n fọwọ yii gbogbo kamẹra alami to wa nibi awọn ẹrọ ATM, eyi lo mu ki oun fa a le ọlọpaa lọwọ.
Adajọ beere lọwọ Abdullahi pe ṣe loootọ lo n fọwọ yi kamẹra naa, o ni loootọ ni, ṣugbọn alantakun loun fẹẹ fọwọ re ti ọwọ oun fi n yi kamẹra. O tun sọ fun adajọ pe oun ko gbadun daadaa, awọn obi oun sọ pe aye n ṣe oun, kọda oun le maa ba gbogbo nnkan to wa layiika jẹ ti kinni naa ba gun oun tan nigba miiran
Iṣẹ birikila ni afurasi naa ni oun n ṣe, o ni owo loun fẹẹ gba lẹnu ATM, ṣugbọn oun gbagbe kaadi sile ni wọn ko ṣe ba a lọwọ oun.
Adajọ Lawal Ajibaye gba beeli afurasi naa pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000), pẹlu oniduuro meji to jẹ mọlẹbi rẹ, lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2022 .