Kawọn to n yọ nipa beeli Baba Ijẹṣa yọ mọ niwọn, nitori ki i ṣe opin ẹjọ naa-Iyabọ Ojo

Faith Adebọla

Bawọn agbaagba ẹgbẹ yii ṣe n ju fidio wọn saye lọjọ Satide naa ni Iyabọ Ojo paapaa ṣare ṣe fidio tiẹ lati fun wọn lesi. Obinrin yii loun ko ba tija wa lasiko yii, alaye loun fẹẹ ṣe lori ọrọ Ọlọfaana ati TAMPAN, pẹlu ti Baba Ijẹṣa ati Yọmi Fabiyi.

Ọrọ Alagba Ọlọfaana n’Iyabọ fi ṣide alaye ẹ. O loun ko fẹẹ sọ pe agbalagba n parọ, ṣugbọn ko sibi kan toun ti daṣa ‘ẹ bọọlẹ nibẹ’ ti baba naa loun da foun nigba to pe oun lori foonu.

Iyabọ Ojo sọ pe, “Mi o ki i lo iru ede bẹẹ, mi o tiẹ mọ nnkan ti wọn n sọ pe mo ni kawọn sọkalẹ ninu mọto abi nnkan. Ọrọ Yọmi Fabiyi ati Baba Ijẹṣa ni wọn pe mi fun. Wọn ni ki n ma da Yọmi lohun fawọn ohun to n sọ si mi, mo dẹ ni rara, mi o le ma da a lohun, o yẹ ko maa gbesi ọrọ ẹ ni.

“Wọn tun ni awọn n paṣẹ fun mi gẹgẹ bii baba, pe ki n jawọ ninu keesi Baba Ijẹṣa, mo dẹ beere lọwọ wọn pe to ba jẹ ọmọ wọn ni nnkan yii ṣẹlẹ si nkọ. Niṣe ni wọn dakẹ lọ gbari, ti wọn o sọrọ mọ. Emi o pa foonu mọ wọn leti, nigba to ya, ipe yẹn lo ja funra ẹ. Ṣugbọn tẹ ẹ ba ro pe mo ri yin fin, Baba, ẹ ma binu’’

Lori awọn agba TAMPAN to pepade, ti wọn si darukọ ẹ nipa ọrọ Baba Ijẹṣa yii, Iyabọ ni oun mọ awọn agba ẹgbẹ to jẹ ẹyin oun ni wọn wa gbagbaagba, to jẹ niṣe ni wọn n sọ foun lẹyin pe awọn laiki boun ṣe taku ti ọrọ Baba Ijẹṣa yii, ti wọn n sọ pe koun ma jawọ o, oun kare.

O ni awọn agba yii tiẹ tun maa sọ foun pe awọn ko le jade sọrọ ni o, nitori ẹnu aye, ṣugbọn awọn wa lẹyin oun bii ike ni.

Obinrin yii ni ṣugbọn o ṣe ni laaanu, pe awọn mi-in ninu wọn naa ni wọn tun de lokeṣan ere ti wọn n sọrọ oun lẹyin, ti wọn n sọ pe boun ṣe duro ṣinṣin lori ọrọ yii ko daa.

O lawọn toun ko tiẹ rokan pe wọn le maa sọrọ oun laidaa loun ba nidii ẹ loko ere, wọn aa sọ omi-in loju oun, wọn aa sọ omi-in lẹyin, awọn to jẹ toun yoo si waa sọ foun.

Oṣere yii ni, nitori awọn nnkan bayii loun ko ṣe darapọ mọ TAMPAN nigba ti wọn yapa kuro lara ANTP. O loun kọṣẹ lọdọ awọn ọga oun, Abbey Lanre ati Alaaji Yinka Quadri, l’Ebute-Mẹta, ṣugbọn oun ko ba wọn ṣe TAMPAN, nitori oun ko le ri ohun ti ko tọ koun dakẹ, beeyan ba si sọrọ, yoo di wahala, ohun to jẹ koun duro lori ọwọ oun niyẹn, to jẹ Pricilia ati Festus (awọn ọmọ ẹ) loun fi ṣe ọrẹ ati ẹgbẹ oun.

Lakootan nipa TAMPAN, Iyabọ ni nigba tawọn ọjẹwẹwẹ onitiata kan n gbe fidio jade lori ayelujara, ti wọn n bu oun ṣakaṣaka, TAMPAN ko pepade, wọn ko gbe ofin kalẹ, wọn ko si ba wọn wi, bẹẹ wọn ri i.

O loun ko ba TAMPAN ja o, ṣebi awọn ọrẹ oun wa nibẹ. Ṣugbọn ẹgbẹ naa nilo ki wọn tun awọn nnkan kan ṣe. Bi wọn ba si ro pe oun ṣẹ wọn, ki wọn ma binu.

Ṣugbọn nipa jijawọ lori keesi yii, Iyabọ loun o ni i jawọ o. O ni ki i ṣe pe oun koriira Baba Ijẹṣa, iwa to hu loun ko nifẹẹ si. Oun fẹ ki ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinla tọrọ kan naa ri idajọ ododo gba, oun si mọ pe yoo ri i.

Iya Priscilia ni kawọn ọmọ Naijiria to n yọ pe wọn fi Baba Ijẹṣa silẹ ma yọ mọ,  beeli ki i ṣe iyọnda alailẹṣẹ lọrun, fungba diẹ ni.

O lo digba ti kootu ba dajọ ki kaluku too mọ ibi tẹjọ n lọ.  Bẹẹ lo ni ki Yọmi Fabiyi naa maa ṣe tiẹ niṣo, gbogbo bo ṣe n fi oun pero soju opo ayelujara ẹ ko ṣe nnkan kan.

O ni ki Yọmi mu ẹri wa nipa ibi toun ti ni oun yoo pa Baba Ijẹṣa bi kootu ba fi le yọnda ẹ, ko sibi toun ti sọ ohun to jọ bẹẹ rara.

Ọrọ Yọmi ki i ṣe asiko yii gẹgẹ bi Iyabọ Ojo ṣe wi, o ni tiẹ di ọjọ mi-in, ọjọ ire.

 

Leave a Reply