Kayeefi! Awọn agbebọn ji ọba ati olori rẹ gbe lọ

Adewale Adeoye

Ọba alaye kan, Ọba Jibril Mamman, to jẹ olori ilu Gurku, nijọba ibilẹ Karu, nipinlẹ Nasarawa, ati iyawo rẹ, Abilekọ Hajiya Sa’adatu Wasiri, lawọn agbebọn kan ti ji gbe laafin wọn, ti ko si sẹni to mọ ibi ti wọn wa titi asiko ta a n kọ iroyin yii.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ laabi ọhun waye ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii. Gbara tawọn agbebọn naa wọnu ilu ọhun ni wọn ti bẹrẹ si i yinbọn soke gbau-gbau lati da ipaya nla silẹ laarin ilu naa. Taarata ni wọn gba aafin ọba alaye naa lọ, bi wọn ṣe foju kan ọba naa ati olori rẹ ni wọn ti ji awọn mejeeji gbe sa lọ, ti wọn si gbe wọn gba ẹyin odi ilu naa. Nitori pe oru ni iṣẹlẹ naa waye, to si tun jẹ ojiji, ni ko jẹ kawọn araalu naa dide iranlọwọ si ọba yii, ti wọn fi ri i gbe sa lọ.

Ẹnikan to jẹ araalu naa to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ko sẹnikankan to jade rara lakooko tawọn agbebọn ọhun wọlu wa, gbogbo ilu ti da patapata, tawọn kọọkan ti sun ko too di pe awọn ọdaran naa ya wọlu wa, ti wọn si ji ọba yii gbe sa lọ.

‘A n fi akoko yii bẹ awọn alaṣẹ ijọba orileede yii pe ki wọn wa nnkan ṣe sọrọ eto aabo orileede yii, ki i ṣohun to daa rara bawọn agbebọn ṣe waa ji wa lọba gbe sa lọ, ti ko si sẹni to mọ ohun ti ọba naa ṣe fun wọn.

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, awọn agbebọn naa ko ti i pe ẹnikẹni lati beere ohun ti wọn fẹẹ gba lọwọ wa’.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Rahman Nansel, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye.

O ni, ‘Awọn kan lo pe wa ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaale ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, pe awọn agbebọn ti waa ji wọn lọba gbe sa lọ niluu naa, loju-ẹsẹ ni Kọmiṣanna Maiyaki Babaa, ti sọ pe kawọn ọlọpaa lọọ gba ọba alaye naa ati iyawo rẹ silẹ, gbogbo inu igbo keekeeke ati gbogbo abẹ apata to wa lagbegbe naa pata la ti wa daadaa, ṣugbọn a ko ti i ri wọn gba silẹ. Koda, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa ti tun da ikọ ọlọpaa miiran sita bayii lati ṣawari wọn, o si daju pe a maa too ri wọn gba silẹ laipẹ yii.

Leave a Reply