Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu ọkunrin ọmọ ilẹ Olominira Bẹnẹ kan torukọ rẹ n jẹ, Adamu Sabi, niluu Moshe, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara, fẹsun pe o ba iya to bi i ninu Fati Sime, lo pọ titi to fi bi ọmọ mẹta fun un.
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin lori iṣẹlẹ yii. O ṣalaye pe iya to bi Adamu ninu ti bi ọmọ mẹta fun un, ati pe olori ileto kan, Malam Bandele, niluu Mosher, nijọba ibilẹ Kaiama lo mu ẹsun lọ sọdọ ajọ ọhun pe ṣe ni ọkunrin naa mu iya rẹ gẹgẹ bii iyawo, to si n ba a laṣepọ, to tun n bimọ fun un, idi niyi ti ajọ naa ṣe lọọ mu arakunrin ọhun, to si ti wa ni galagala ajọ naa.
Afọlabi tẹsiwaju pe Adamu to jẹ afurasi ati aburo rẹ ti wa lahaamọ tori pe awọn mejeeji ati iya wọn ko niwee igbeluu Naijiria, to si ni iwadii yoo maa tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.