Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Iwa ọdaju ti ọkunrin kan, Kẹhinde Oke, hu loṣu kejila, ọdun to kọja, lo pada koba a laipẹ yii lẹyin to tun lọọ digun jale nibi kan, tọwọ si tẹ ẹ.
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, ọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, lẹni ọgbọn ọdun naa lọọ ja Purofẹsọ Michael Ige lole niluu Ilawẹ-Ekiti, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Ekiti.
Lalẹ ọjọ naa lo gba kọmputa agbeletan kan ati foonu, bẹẹ lo ba mọto baba naa jẹ, eyi towo ẹ to miliọnu kan naira.
Bakan naa lo tun fipa ba obinrin ẹni ọdun marundinlọgọta kan lo pọ ninu ile kan naa ko too sa lọ.
Laipẹ yii ni wọn sọ pe ọwọ tẹ Kẹhinde lẹyin to tun lọọ digun jale nibi kan, nigba tawọn ọlọpaa si n ṣewadii ni wọn ba awọn ẹru purofẹsọ to ja lole lọwọ ẹ.
Eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa wọ ọ lọ si kootu Majisreeti ilu Ado-Ekiti, nibi ti wọn ti fẹsun idigunjale ati ifipabanilopọ kan an.
Inspẹkitọ Caleb Leramo sọ pe awọn ẹsun naa ta ko ofin idigunjale ati nnkan ija oloro lilo, bẹẹ lo tun nijiya ninu ofin to de ifiyajẹni. O ni ẹka to n ṣegbẹjọ araalu (DPP), lo le da si ọrọ naa, idi niyi toun fi fiwe ẹjọ naa ṣọwọ si wọn fun igbesẹ to kan.
Nigba to n gbe ipinnu ile-ẹjọ kalẹ, Majisreeti Lawal Abdulhamid paṣẹ pe ki Kẹhinde lọọ jokoo sọgba ẹwọn di ọgbọnjọ, oṣu yii, ti kootu naa yoo tun mẹnu ba ọrọ rẹ pẹlu ilana ti DPP ba gbe kalẹ.