Kelechi gun ọrẹbinrin ẹ pa, lo ba tọju oku ẹ sabẹ bẹẹdi!

Gbenga Amos, Ogun

 Idowu Buhari ni wọn porukọ ọdọmọbinrin arẹwa tẹ ẹ n wo fọto ẹ yii, ileewe Poli Gateway, iyẹn Gateway Polytechnic, to wa ni Ṣaapade, l’Ode-Rẹmọ, nijọba ibilẹ Ṣagamu, ipinlẹ Ogun, lọmọbinrin naa ṣẹṣẹ wọle si fun ipele ẹkọ giga ti wọn n pe ni HND ninu imọ ibaraalu-sọrọ (Mass Communication) nileewe ọhun. Amọ ọrẹkunrin ẹ ti wọn ni wọn ṣẹṣẹ pade ara wọn laipẹ yii, Kelechi, ti da ẹmi ọmọbinrin yii legbodo, o ṣeku pa a lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgọn, oṣu Kọkanla yii, o si tọju oku rẹ sabẹ bẹẹdi ọrẹ ẹ, o n reti ki ọjọ bora ko le ri ọna lọọ ju oku naa sigbo, laṣiiri ẹ fi tu.

Ọmọọlewe ọhun kan ti ko fẹ ka darukọ ẹ sọ f’ALAROYE pe lati bii ọjọ meji si mẹta sẹyin loloogbe yii ti wa pẹlu ọrẹkunrin ẹ ọhun, ọmọkunrin naa ki i ṣe akẹkọọ ileewe wọn ni tiẹ, tori ẹ, wọn ni ile ọrẹ ẹ kan lo gbe ọmọbinrin yii lọ, ibẹ si ni wọn wa, ti wọn jọ n gbadun ara wọn.

Lọjọ tiṣẹlẹ yii waye, a gbọ pe Kelechi lọọ ra ounjẹ ọsan wa fun ọrẹbinrin ẹ ni ile-ounjẹ OTP to wa l’Ode-Rẹmọ. Ko pẹ lẹyin tọmọbinrin naa jẹun tan ni nnkan gbẹyin yọ, wọn ni afurasi ọdaran yii gun ọmọbinrin naa lọbẹ, ẹjẹ si n jade nimu ẹ. Wọn ni wọn ba ike funfun kinniwin mẹrin kan ninu yara ọhun ti wọn sọ pe ọmọkunrin yii fẹ gbe ẹjẹ ẹni to pa naa si, wọn lo fẹẹ fi i ṣe oogun owo ni, wọn lọmọ ‘Yahoo’ ni.

Amọ, awọn kan ni ko ri bẹẹ, wọn ni ija lo de lorin dowe laarin Kelechi ati Idowu lẹyin ti wọn jẹun tan, a o mọ pato ohun to faja, ṣugbọn wọn ni wọn wọya ija, nibi ti wọn si ti n ja, ti wọn ti da gbogbo inu yara ọhun ru wuruwuru, Kelechi fibinu ti ọmọbinrin naa lu iganna lojiji, o si ṣe e leṣe. Wọn ni bo ṣe digbo lulẹ ni ẹjẹ bẹrẹ si i jade ṣuruṣuru n’imu ẹ. Eyi ti wọn iba si fi ṣaajo ẹ, niṣe ni jẹbẹtẹ gbọmọ le bọifurẹndi yii lọwọ, titi tọmọbinrin naa fi dakẹ.

Lẹyin to dakẹ ni Kelechi wọ oku ẹ sabẹ bẹẹdi, wọn loo fẹẹ ṣe ọrọ naa lokuu oru, ṣugbọn aṣiri pada tu.

Ninu fidio kan ti wọn fi lede, a ri i bawọn ọlọpaa ṣe lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran yii, wọn fi ankọọfu si i lọwọ, ti wọn n mu un lọ sinu ọkọ ọlopaa ti wọn gbe wa, bẹẹ la tun ri i bi wọn ṣe n gbe oku ọmọbinrin naa jade, tawọn eeyan si n diwọ mọri, ti wọn n ṣedaro loriṣiiriṣii.

Ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko, lawọn obi oloogbe yii n gbe, wọn si ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii.

Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, nibi tiṣẹle naa ti waye, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o loun ti gbọ si i, ṣugbọn awọn ṣi n ṣewadii lati mọ bọrọ ọun ṣe jẹ gan-an.

Leave a Reply