Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kootu Majisireeti kan to wa niluu Ondo, ti dajọ ẹwọn ọdun mẹta fun ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Handsome Kenneth, ti wọn fẹsun kan pe o ji foonu onifoonu l’Ondo.
Ni ibamu pẹlu ẹsun ti wọn fi kan an nile-ẹjọ, ọdaran ọhun ni wọn lo ji foonu Infinix S4 kan ti wọn lo jẹ ti ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Akinladejọ Felix, ninu ile-itura Akiavic, eyi to wa lopopona Marosẹ Ademulẹgun, niluu Ondo, ni nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
Ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan an ni Agbefọba, Benard Ọlagbayi ni o ta ko abala ọrin-le-lọọọdunrun-le mẹta (383) iwe ofin tipinlẹ naa n lo, bẹẹ lo tun ni ijiya to lagbara diẹ ninu labẹ abala irinwo-din-mẹwaa (390) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Ni kete ti wọn ti ka ẹsun ọhun tan ni olujẹjọ naa ti gba pe oun jẹbi, to si n bẹ ile-ẹjọ naa lati ṣiju aanu wo oun latari ẹsẹ ti oun ṣẹ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Charity Adeyanju ni oun paṣẹ fun olujẹjọ naa ko lọọ fi ẹwọn ọdun mẹta jura tabi ko tete lọọ san ẹgbẹrun lọna ọrin-le-nigba-din mẹta Naira (#277,400) gẹgẹ bii owo itanran.