Ki aṣiri awọn iwa ti Tinubu ti hu sẹyin ma baa tu lo fi n sa nipade ita gbangba-PDP

Monisọla Saka

Alukoro igbimọ to n polongo ibo aarẹ fun Atiku Abubakar ti ẹgbẹ PDP, Kọla Ologbodiyan, ti sọ pe awọn ti mọ idi ti oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu, fi n sa fun ipade ita gbangba ti wọn ti n pe awọn oludjie sipo aarẹ si lati waa sọrọ.

Ẹgbẹ naa ni nitori ki aṣiri awọn iwa buruku ti Tinubu ti hu sẹyin ma baa tu sita ni, nitori o ti mọ pe ko si ki awọn ọmọ Naijiria ma bi oun nibeere lọ si awọn agbọn naa.

Ẹgbẹ PDP ni, ẹru n ba Tinubu ni, nitori o ti mọ pe gbogbo iwa ibajẹ, ajẹbanu, aikun oju oṣuwọn to ati iwa ẹlẹyamẹya to n hu kiri lawọn eeyan maa beere ọrọ nipa rẹ lasiko ijokoo naa.

Ologbodiyan sọ pe Tinubu ko le jokoo sibi iru ipade ifọrọ-jomi toro ọrọ awọn to fẹẹ dupo aarẹ bẹẹ, ko si kọju si awọn araalu lati dahun ibeere lori awọn iwa to ti hu sẹyin bii ibi to ti wa, awọn to bi i, ọrọ Alpha Beta, iyẹn ileeṣẹ olowo-ori to ti n gba obitibiti owo, ati bo ṣe fọwọ fun okoowo, eto oṣelu, ati aye awọn eeyan ipinlẹ Eko lọrun lati ọdun 1999.

‘‘Ẹru n ba a lori bo ṣe fun awọn ara Eko gbẹ fun odidi ọdun mẹjọ, pẹlu oriṣiiriṣii owo-ori to fi n ni wọn lara, ti ko si si ohun gidi kan to ṣee tọka si fun araalu ju ijọba imunisin, kiko awọn ọmọọta atawọn ọmọ ganfe jọ, to waa de bayii to ni oun ni awọn aṣẹyọri gẹgẹ bii gomina laarin ọdun mẹjọ’’.

Ologbodiyan ni ṣe ki i ṣẹ ohun to jọ ni loju, nigba ti Tinubu to pe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ Onitẹsiwaju ba n sa fun ipade iru eyi ti tẹlifiṣan Arise ṣe yii. Ko wa, ko si tun ran aṣoju wa.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla yii, ni ileeṣẹ Arise tẹlifiṣan ati ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Centre For Democracy and Development (CDD), gbe eto ipade ita gbangba kan kalẹ fun awọn oludije sipo aarẹ lorileede wa niluu Abuja.

Ọpọ awọn oludije yii lo wa nibi ipade naa, awọn ti ko si wa ran igbakeji wọn. Ṣugbọn oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ko wa sibẹ, bẹẹ ni igbakeji rẹ naa ko si yọju.

Leave a Reply