Ki awọn ọba wa yee fi oye da awọn ti ki i ṣe ọmọ bibi ilẹ Yoruba lọla mọ-Gani Adams

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams ti sọ pe gbogbo agbara lati daabo bo awọn aala to yi iha Iwọ-Oorun Guusu ilẹ yii ka lo wa lọwọ iran Yoruba, o si sọ pẹlu idaniloju pe ẹgbẹ Oodua Peoples Congress ko ni i laju silẹ ki iru iṣẹlẹ iṣekupani to waye niluu Ọwọ tun ṣẹlẹ mọ nibikibi nilẹ naa.
Aarẹ sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo sọdọ Ataọja tilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji, ṣaaju ipade apapọ awọn ọmọ igbimọ naa to waye niluu Oṣogbo. O sọ pe pe eredi ipade naa ni lati ṣe ilanilọyẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ OPC.
Alakooso apapọ ẹgbẹ naa waa rọ awọn lọba-lọba ki wọn dẹkun fifi oye da awọn ti wọn ki i ṣe ọmọ bibi ilẹ Yoruba lọla, o ni iru iwa bẹẹ le ṣakoba fun aṣa iran naa.
O ni, “Ẹkun Iwọ-Oorun Guusu lagbara lati pinwọ wahala aisi aabo. Ẹgbẹ OPC labẹ iṣakoso mi yoo ṣa gbogbo ipa, labẹ ofin, lati ri i pe iru iṣekupani to ṣẹlẹ niluu Ọwọ ko waye mọ nibikibi ni ẹkun yii.
“Inu mi dun lati sọ fun kabiesi pe a ti n ṣiṣẹ lori ọna ti ibaṣepọ yoo fi wa laarin awọn oṣiṣẹ alaabo ibilẹ (local security) atijọba. A ṣetan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn gomina ilẹ Yoruba lati le ṣeto aabo to peye.
“Ki kabiesi ba wa sọ fun awọn ori-ade wa lati daabo bo aṣa wa, ko ma baa parun. Aṣa ki wọn maa fun awọn ti wọn ki i ṣe ọmọ Yoruba ni oye ta ko aṣa ati iṣe wa”
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Oyetunji fi aidunnu rẹ han si bi eto aabo ṣe mẹhẹ nilẹ Yoruba, o ni pẹlu ohun to ṣẹlẹ niluu Ọwọ yii, o han gbangba pe ilẹ Yoruba ni awọn aṣekupani yii doju kọ bayii.

Leave a Reply