Adewale Adeoye
‘Pẹlu ohun to wa nilẹ yii, inu mi dun gidi pe ki i ṣe dandan mọ rara pe ki aarẹ orileede yii maa lọ soke okun lati maa lọọ gba itoju gẹgẹ bo ti ṣe n waye tẹle. Ojulowo irinṣẹ lo ti wa ninu ọsibitu igbalode ti ọkọ mi kọ siluu Abuja yii, nnkan kan ṣoṣo ti mo lero pe o kan le maa waye lẹkọọkan ni pe ki wọn maa lo pe awọn ogbontarigi onimọ iṣegun oyinbo lati oke-okun lati maa waa ran awọn tilẹ wa lọwọ lẹkọọkan. Ko fi bẹẹ si iyatọ kan lọ titi laarin ohun ta a kọ silẹ yii ati eyi tawọn olori wa gbogbo n lọọ ba loke okun’ Eyi lọrọ to jade lẹnu iyawọ Aarẹ orileede yii, Abilekọ Aisha Buhari, lakooko ti wọn n ṣi ọsibitu igbalode kan tijọba Aarẹ Muhammadu Buhari kọ fawọn olori orileede yii atawọn mọlẹbi wọn gbogbo to n bọ lọna siluu Abuja.
ALAROYE gbọ pe biliọnu mọkanlelogun Naira (N21b) ni wọn na sori kikọ ọsibitu naa, eyi ti wọn sọ pe ko sẹlẹgbẹ rẹ rara nilẹ yii, ati nibi gbogbo nilẹ adulawọ bayii.
Ninu ọrọ rẹ lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori erongba ijọba Buhari lati kọ ọsibitu naa, Abilekọ Aisha Buhari sọ pe ‘Ni koko, ohun to jẹ ki n kan-an nipa fọkọ mi pe ko kọ ọsibitu naa ni pe yoo le ṣanfaani gidi fawọn olori orileede wa gbogbo, atawọn ẹbi wọn lati maa ṣetọju ara wọn nilẹ yii dipo bi wọn ṣe n lọ soke okun nigba gbogbo yii. Ero ọhun wa si mi lọkan ni nnkan bii ọdun mẹfa sẹyin bayii, nigba ti ọkọ mi n fi igba gbogbo lọ soke okun lati lọọ ṣetọju ara rẹ lohun-un. Igba kan tiẹ wa to lo to oṣu mẹta gbako lọhun-un, bẹẹ lawọn kan n sọ pe boya o ti ku ni. Pẹlu ba a ti ṣe kọ ọsibitu yii siluu Abuja fawọn olori orileede yii atawọn ẹbi wọn gbogbo to n bọ lọna, yoo rọrun gidi fun wọn lati maa gba itọju nile lai daamu rara lọ soke okun mọ gẹgẹ bo ti ṣe wa tẹlẹ.
‘‘Loooto ni saa emi pẹlu ọkọ ni ko ni i pẹẹ pari, ṣugbọn inu mi dun pe ohun ti mo dawọ le ni nnkan bii ọdun mẹfa sẹyin bayii ti so eeso rere, mo ṣiṣẹ naa ni aṣepari tan’’.
Ni idahu rẹ si ibeere awọn oniroyin kan pe njẹ ọsibitu naa yoo fopin si bawọn olori orileede wa gbogbo ṣe n lọ soke okun nigba gbogbo tara wọn ko ba ya, Aisha ni, ‘‘Dandan niyẹn, ko yẹ rara mọ kawọn olori orileede wa tun sọ pe awọn n lọ soke okun lati lọọ gba itoju kankan mọ bayii, ọsibitu yii le figa-gbaga pẹlu tawọn oke-okun daadaa. ‘‘Aarẹ Goodluck Jonathan lo kọkọ mu aba kikọ ọsibitu naa wa lọdun 2012, ṣugbọn ko pari rẹ rara, erongba rẹ nigba naa ni pe ka ye fọn owo danu lori ilera awọn olori orileede wa soke okun’’.
Lakooko ti wọn n ṣi ọsibitu igbalode naa, Aarẹ Buhari atawọn eeyan jankan-jankan kaakiri orileede yii lo wa nibẹ. Lara wọn ni olori awọn oṣiṣẹ ninu ijọba Buhari, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, ati Akowe agba fun ile ijọba, Tijani Umar.
Ọdun 2020 ni Aarẹ Buhari buwọ lu kikọ ọsibitu naa, ti wọn si kọ ọ tan ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2022.