Ki i ṣe gbogbo ẹnu-ibode la maa ṣi silẹ- Ọga Kọsitọọmu

Adeoye Adewale

Adele ọga ajọ aṣọbode orile-ede wa, Ọgbẹni Wale Adeniyi, ti sọ pe ki i ṣe gbogbo awọn ẹnu ibode to wọ ilẹ wa lawọn ti ṣi silẹ, tabi lawọn maa tun ṣi ti akoko ba to.

Adeniyi ni ajọ Kọsitọọmu ṣi n ro aba  lati ṣi awọn ibode naa gẹgẹ bii ireti awọn araalu atawọn oniṣowo kọọkan lọwọ ni.

Ọga agba ajọ ọhun sọrọ yii di mimọ niluu Abuja, lẹyin to pari ipade pajawiri kan to ṣe pẹlu olori orile-ede yii, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, lọjo Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii.

Adeniyi ni ko sẹni ti ko mọ pe awọn ti ṣi awọn ẹnuubode kọọkan lorileede yii lati ọdun to kọja lọ yii, tawọn si tun ti n gbe e yẹwo bayii lati tun ṣi awọn miiran lẹyin tawọn ba gbe e yẹwo daadaa tan.

O ni, ‘’Ohun ti ma a sọ fun gbogbo araalu ni pe ki i se gbogbo ẹnu-ibode to wọlu pata la ti ṣi silẹ bayii, awọn ohun tijọba fofin de pe wọn ko gbọdọ ko wọle ṣi wa bẹẹ’’.

Bẹ o ba gbagbe, ọdun 2018 nijọba Buhari paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ẹnu-ibode to wọ orile-ede Naijiria pa patapata, kawọn ọja kọọkan tabi ohun ọgbin tawọn agbẹ orile-ede wa n gbin bii iresi, le jẹ itẹwọgba daadaa laarin awọn ọmọ orile-ede wa lakooko naa. Ṣugbọn nigba to di ọdun 2022, awọn alaṣẹ ijọba apapọ ilẹ wa paṣẹ pe ki wọn ṣi awọn ẹnu-ibode kan, kawọn ọja kọọkan le wọlu.

‘‘Mẹrin la kọkọ ṣi silẹ ninu awọn bode yii, lẹyin naa la tun ṣi meji miiran si i. Bo ti ṣe wa niyẹn latigba naa.

‘‘Eto n lọ lọwọ labẹnu bayii lati ṣagbeyẹwo lori ba a ti ṣe maa ṣi awọn kọọkan si i bayii. Ohun ta a n yẹ wo ko ju bi ṣiṣi ẹnu-ibode ọhun ko ṣe ni i ba nnkan ta a ri ko too di pe, a ti wọn pa tẹlẹ jẹ.

Leave a Reply