Ki Tinubu ro o daadaa o, abadofin owo-ori tuntun yii maa fiya jẹ awọn eeyan Oke-Ọya- Zulum 

Adewale adeoye

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, ti ni awọn ara Oke-Ọya ko ta ko pe ki olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ma lọ ọwọ agbara rẹ nipa abadofin eto owo-ori to gbe siwaju awọn aṣofin agba l’Abuja, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo to daju ṣaka nibẹ ni pe awọn araalu lo maa jiya gbogbo ohun to ba tidi rẹ yọ.

O ni ogunlọgọ awọn ọmọ orileede Naijiria ni abadofin eto naa maa ṣakoba fun bi awọn aṣofin ba le buwọ lu u pe ko dofin gẹgẹ bii erongba Tinubu.

Zulum sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n sọrọ lori Channels TV, l’Abuja, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni mi, ti ẹ ba fẹẹ ka gomina meji to ti n ṣe atilẹyin fun Tinubu lati ọdun 2019 si 2023 yii, ẹ le darukọ Ọjọgbọn Zulum si i. Mo wa ninu awọn gomina to kọkọ jade sita gbangba pe ipo agbara gbọdọ pada si isalẹ. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe awọn kan ti sọ fun Aarẹ pe awọn eeyan Oke-Ọya koriira rẹ, bo tilẹ jẹ pe ida ọgọta ibo (60.2),to gbe e wọle, awọn eeyan Oke-Ọya lo di i fun un.

‘’Ọpọlọpọ aigbọra ẹni ye lo ti waye lori ọrọ atunṣe owo-ori yii ninu ipade apapọ awọn igbimọ aṣẹjọba, a si ti rọ ijọba pe ki wọn so o rọ ki ipade mi-in fi waye laarin awọn alẹnulọrọ gbogbo. Ibi ti awa duro si niyi’’.

Zulum waa bẹ awọn gomina ẹgbẹ rẹ, awọn alẹnulọrọ gbogbo nilẹ Hausa, pe ki wọn ma ṣe gba ofin naa wọle, o ni bi wọn ba gba a, akoba nla ni yoo ṣe si ọrọ-aje awọn eeyan Oke-Ọya.

 

Gomina Borno yii ni, ‘’A mọ daju pe agbara nla, agbara to bori agbara, lo wa lọwọ olori orileede yii, a si ti gba fọgaa wa gẹgẹ bii aṣa awọn kan. Bi Aarẹ ba fẹẹ lo gbogbo agbara rẹ lati ri i pe awọn aṣofin agba l’Abuja fontẹ lu abadofin naa fun un, o mọ nnkan to maa ṣe. Mi o jiyan nipa rẹ, ṣugbọn atunbọtan ati ipalara nla to maa fa fawọn araalu lo n kọ mi lominu bayii. Loju iwoye mi, ipinlẹ Eko ati Rivers, nikan ni eto naa maa wulo fun gidi, akoba nla gbaa lo maa fa fawọn eeyan  Oke-Ọya nibi. Idi ree ta a ṣe n rọ Aarẹ pe ko fun wa lasiko diẹ si i ka fi gbe ọrọ naa yẹwo daadaa laarin ara wa, ko too di pe wọn maa sọ aba ọhun di ofin lorileede yii.

‘’A n rọ ijọba apapọ pe ki wọn dawọ abadofin ọhun duro, ko sohun to yẹ kọrọ naa fi jẹ waduwadu tani kanju-n-kanju rara, gbogbo wa pata l’Oke-Ọya la gbọdọ gbe e yẹwo daadaa laarin ara wa, ka mọ koko ohun ti kinni ọhun da le lori, ipalara nla to maa fa fun wa ko too di pe wọn maa sọ ọ dofin.

‘’Koko kan wa ninu abadofin ọhun to jẹ pe iwọnba owo tipinlẹ kọọkan ba pa wọnu apo ijọba apapọ orileede yii ni wọn maa fi fun un ni ipin tiẹ. Loootọ mi o ki i ṣe onimọ ijinlẹ nipa eto ọrọ-aje, ṣugbọn loju iwoye mi ati ninu iwadii ta a ṣe, ipinlẹ Eko ati Rivers, nikan ni abadofin ọhun maa ṣafaani fun ju lọ. Awọn ipinlẹ iyooku lorileede yii maa jiya gidi ni, awọn araalu to pọ yanturu ni wọn si maa fori fa wahala ọhun bi abadofin ọhun ba dofin gẹgẹ bii erongba Aarẹ Tinubu’’.

Tẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta ti wahala ọrọ ofin owo-ori tuntun naa ti n ja ran-in kaakiri orileede yii. Bi awọn gomina atawọn aṣofin kan ṣe fọwọ si i, bẹẹ lawọn kan ninu wọn n ta ko o. Diẹ lo si ku ki wọn tutọ sira wọn loju nileegbimọ aṣofin agba lọsẹ to kọja yii nigba ti ọkan ninu awọn aṣofin naa, Ọpẹyẹmi Bamidele lati ipinlẹ Ekiti, mu aba wa pe ki wọn gba awọn alẹnulọrọ lori ọrọ owo-ori kan laaye lati waa ṣalaye nipa ofin naa.

Latigba naa ni ọkan-o-jọkan ariwo ti n lọ, ti awọn aṣofin lati Oke-Ọya si ti n sọ pe ki wọn ma fi waduwadu bọ ofin naa, ki wọn ni suuru. Bẹẹ lawọn agbaagba atawọn alẹnulọrọ nilẹ Hausa yii n sọ pe awọn ko fọwọ si ofin naa, nitori ifasẹyin to maa ko ba awọn.

Ọkan ninu ohun to wa ninu abadofin owo-ori tuntun yii ni pe bi ipinlẹ kọọkan ba ṣe pawo wọle sapo ijọba apapọ si ni owo ti yoo maa tẹ wọn lọwọ yoo ṣe maa pọ si. Aaye pe ki ipinlẹ kan pawo pupọ, ṣugbọn ki wọn sọ pe nitori pe wọn ko to awọn ipinlẹ ti ko pawo pupọ, awọn ipinlẹ ti wọn ko pawo pupọ, ṣugbọn ti wọn ni ero rẹpẹtẹ yoo gbowo ju wọn lọ ko ṣẹlẹ mọ.

Lara nnkan mi-in to tun wa ninu abadofin ọhun ni ominira ti yoo wa fun awọn olokoowo keekeeke ti owo ti wọn fi n ṣowo ko to nnkan, ti okoowo ati iṣẹ ti wọn n ṣe ko fi bẹẹ pọ, tabi awọn oṣiṣẹ ti owo wọn ko to iye ti ijọba fọwọ si gẹgẹ bii owo-ori to kere ju lọ, wọn ko ni i san owo-ori mọ.

Ṣugbọn ilu ganagan ni ọrọ atunṣe owo-ori yii, ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomi-in pẹlu bi awọn ẹya Yoruba atawọn Ibo ṣe ni awọn fọwọ si aba ti Tinubu gbe siwaju awọn aṣofin yii lati di ofin.

Ni bayii, wọn ti ka ofin naa fun igba keji nileegbimọ aṣofin agba, wọn si ti taari rẹ si igbimọ to n mojuto ọrọ owo-ori atawọn ohun to jẹ mọ ọn nileegbimọ naa lati ṣagbeyẹwo rẹ, ki wọn si mu aba wa. Ọsẹ mẹfa ni wọn ni lati ṣiṣẹ lori rẹ, ki wọn si gbe ipinnu wọn lori rẹ siwaju awọn aṣofin.

 

Leave a Reply