Aderounmu Kazeem
Ikilọ ti lọ sọdọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Eko pe ko gbọdọ si iwọde tabi apejọpọ kankan lati ọdọ ẹnikẹni labẹ bo ṣe wu ko ri nipinlẹ Eko lasiko yii. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ si ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Ọga ọlọpaa naa ni àpá eyi to ṣẹlẹ laipẹ yii ṣi wa lara gbogbo olugbe ipinlẹ naa ti ko ti i jina. O fi kun un pe iroyin kan ti tẹ awọn lọwọ pe awọn kọlọransi kan ti n mura lati tun ṣe iwọde to jẹ mọ ọrọ SARS, eyi ti ijọba ka si ohun to buru, ti ko si mu iwulo tabi anfaani kankan wa.
Adejọbi ni oun lo anfaani naa lati sọ fun gbogbo araalu pe ẹnikẹni, akojọpọ eeyan tabi awọn akẹkọọ ko gbọdọ kora jọ pọ pe awọn fẹẹ ṣe iwọde kankan bo ṣe wu ko ri, ibaa jẹ iwọde alaafia tabi eyikeyii.
Alukoro ọlọpaa yii ni gbogbo ọna ni awọn ọlọpaa ati ileeṣẹ agbofinro yoo fi dena iwọde yoowu to le ko wahala ba araalu tabi to le da rogbodiyan silẹ.
O waa rọ awọn obi ati alagbatọ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ki wọn ma ṣe lọwọ si iwọde kankan nitori o ṣee ṣe ki awọn ọmọ ita ja iwọde yii gba, ki wọn si fi da wahala silẹ bii eyi ti a ṣẹṣẹ n bọ ninu rẹ yii.