Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe latari akọlu ti awọn ọmọọta n ṣe si awọn ọlọpaa atawọn ọmọ orileede yii ti wọn ko mọwọ mẹsẹ, ti wọn n gbe ipinlẹ Eko, leyii to mu ki ijọba ipinlẹ Eko paṣẹ konilegbele oni wakati mẹrinlelogun kaakiri ipinlẹ naa, aṣẹ yii yoo mulẹ lati akoko naa lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
‘Eyi ni lati sọ fun gbogbo eeyan pe ko gbọdọ si ipejọ pọ, iwọde tabi ifẹhonu han eyikeyii nibikibi nipinlẹ Eko.
‘Fun idi eyi, gbogbo ẹṣọ aabo ni wọn ti ro lagbara, ti wọn si ti ṣetan lati ri i pe ofin yii mule kaakiri ipinlẹ Eko.
‘Bakan naa lo dun wa lati fi iṣẹlẹ agọ ọlọpaa ti wọn jo ni Orile ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ yii, nibi ti wọn ti ṣe awọn ọlọpaa leṣe mulẹ, ti iroyin ta a ko ti i fidi rẹ mulẹ si sọ pe ọlọpaa kan ku lasiko iṣẹlẹ naa.
‘Ohun to daju ni pe awọn ọmọ ganfe ti ja eto iwọde SARS yii gba mọ awọn to n ṣe e lọwọ, ti wọn si fẹẹ fi da wahala silẹ kaakiri ipinlẹ Eko, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa yoo lo gbogbo ọna to tọ labẹ ofin lati fopin si idarudapọ, wahala ati irukerudo ti wọn le fẹẹ da silẹ.
‘Bo tilẹ jẹ pe ileesẹ ọlọpaa ko lodi si ẹtọ ọmọniyan tabi ominira ẹnikẹni labẹ ijọba awa-ara-wa, sibẹ, a rọ awọn araaalu lati tẹle ofin konilegbele yii, ki wọn si yẹra fun iwa jagidijagan, nitori ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i faaye gba eleyii rara.